Awọn ajinigbe tun ji soja atawọn meji mi-in gbe n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ọrọ awọn ajinigbe nipinlẹ Ọyọ bọna mi-in yọ lọsẹ yii pẹlu bi wọn ṣe ji odidi ṣọja gbe pẹlu eeyan meji mi-in.

Ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ kejila, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde, to kọja, la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye labule ti wọn n pe ni Onipẹẹ, lọna to ti Ibadan lọ s’Ijẹbu-Ode.

Iyaale ile ni wọn pe awọn mẹtẹẹta. Eyi to n jẹ Bọla Ogunrinde ninu wọn ni wọn pe ni ṣọja. Orukọ awọn yooku ni ṣọja kan, Abọsẹde Adebayọ ati Abilekọ Ọkẹowo.

Ọna Ijẹbu-Ode ni wọn n lọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota ti nọmba rẹ jẹ AGL 66 FY. Ogunrinde, ṣọja inu wọn to ni ọkọ naa lo wa nnkan ẹ ti awọn mẹtẹẹta si jọ n takurọsọ bi wọn ṣe n lọ ki awọn jagunlabi too ya lu wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fakọroyin wa lori ẹrọ ibanisọrọ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe awọn araadugbo ọhun lo sare lọọ fiṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti ni teṣan ọlọpaa to wa ni Idi- Ayunrẹ, n’Ibadan.

O ni akojọpọ awọn ọlọpaa, awọn agbofinro mi-in pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ ti fọn da si gbogbo inu igbo to wa nijọba ibilẹ naa ati ibi gbogbo to ṣee ṣee ṣe ki wọn ti ri awọn obinrin naa gba silẹ ki wọn si ri awọn ọdaran naa mu.

 

 

Leave a Reply