Awọn ajinigbe ya wọ otẹẹli, wọn ji ẹni to ni in, iyawo atawọn ọmọ rẹ mẹta l’Ajaawa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọrọ awọn ajinigbe ti waa doju ẹ ni ipinlẹ Ọyọ bayii pẹlu bi wọn ti ṣe ya wọ ileetura kan ti wọn n pe ni Agbo Hotel, niluu Ajaawa, ti won si ji odidi eeyan meje gbe. Mọlẹbi kan naa si lawọn mejeeje.

Ajaawa jẹ ọkan ninu awọn ilu to wa nijọba ibilẹ Ogo-Oluwa, nipinlẹ Ọyọ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, bi awọn ajinigbe ti wọn ko din ni meje yii ṣe de Agbo Hotel, to wa lẹyin CAC Primary School, lọna to ja si ilu Iwo ati Ejigbo, nigboro ilu naa ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun (24) oṣu karun-un ọdun 2021 yii, ni wọn yinbọn soke leralera lati da ipaya si ẹni gbogbo to wa nileetura naa lọkan.

Ọdọ ẹni to ni otẹẹli ọhun, Ọnarebu Olukunle Oyedokun atiyawo ẹ, Abilekọ Busayọ Oyedokun, ni wọn kọkọ lọ taara. Lẹyin ti wọn sọ awọn mejeeji saarin tan ni wọn fi ibọn ti wọn nipakọ lọ sọdọ awọn mọlẹbi wọn yooku, ti wọn si ji awọn papaa gbe.

Ninu awọn awọn marun-un ti wọn ko lọ sinu igbo pẹlu wọn la ti ri awọn ọmọ tọkọ-tiyawo yii meji, Abilekọ Ọmọriyeba ati ọmọbinrin rẹ to n jẹ Abilekọ Adeṣẹwa ti ko ju ọmọọdun mẹwaa lọ. Orukọ ọmọ wọn keji ni Abilekọ Oluwajuwọnlọ

Awọn yooku ni Abilekọ Juliana Oyedokun to jẹ iyawo aburo ọnarebu naa pẹlu ọkan ninu awọn alejo ti wọn wọ̀ sileetura ọhun lasiko naa.

ALAROYE gbọ pe gbogbo eeyan to wa nibẹ lawọn ọbayejẹ eeyan naa iba ji gbe bi ko ṣe pe ori ko awọn meji yooku yọ, ti wọn ribi ba sa lọ mọ awọn ọdaju eeyan ọhun lọwọ.

Wọn ni nitori ipade ti awọn Oyedokun n ṣe lori ayẹyẹ eto isinku ẹni wọn kan to ku laipẹ yii, to yẹ ko waye lọjọ Ẹti, Jimọ, ọsẹ yii, lẹsẹ gbogbo wọn ṣe ko sileetura naa lati jiroro lori bi wọn ṣe fẹ ki eto ọhun lọ.

Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn mọlẹbi kan ṣe fidi ẹ mulẹ, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, o lawọn ajinigbe ọhun pe awọn ẹbi wọn pe miliọnu mẹẹẹdogun naira lawọn yoo gba ki awọn too le tu awọn eeyan wọn silẹ ko too di pe wọn fara mọ ẹbẹ idile naa lati gba miliọnu meji ataabọ naira bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i sanwo naa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Iwadii akọroyin wa fìdí ẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa Ajaawa ati agbegbe ẹ, pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ ilu naa ti wa ninu idaamu bayii lati ri i pe wọn yọ awọn eeyan naa kuro nigbekun awọn olubi ẹda naa.

 

 

Leave a Reply