Ọlawale Ajao, Ibadan
Bi awọn ajinigbe ba le wọnu ile ti wọn n fi ọdẹ ṣọ, ti wọn si ri onile ọhun ji gbe, afi ki eeyan ti ko rowo gbọdẹ kun fun igbiyanju ati adura daadaa pẹlu bi awọn janduku agbebọn ṣe wọle tọ obinrin kan lọ, ti wọn sì jí í gbe lẹyin ti wọn yinbọn pa ọdẹ to n ṣọ ile naa.
Niluu Iṣẹyin, nipinlẹ Ọyọ, niṣẹlẹ yii ti waye nigba ti awọn alailaaanu eeyan ọhun yinbọn pa ọdẹ to n ṣọ ile, ti wọn si wọnu ile lọọ ji obinrin onile naa gbe lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindilogun (16), oṣu Karun-un, ọdun 2024 ta a wa yii.
Obinrin ti wọn ji gbe yii, Abilekọ Sekinat, lo jẹ ìbátan fun Amofin-Agba Ahmed Raji ti i ṣe agba ọjẹ agbẹjọro nilẹ yii.
Ọkada lawọn obilẹjẹ ẹda ọhun gun lọ sile obinrin naa, ṣugbọn ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti wọn n pe ni Lexus ni wọn fi gbe e lọ síbi tí ẹnikẹni kò ti i mọ titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn agbofinro ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii, wọn si ti palẹ oku ọdẹ ti wọn yinbọn pa ọhun mọ.
Awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ lori iṣẹlẹ yii lati gba obinrin naa silẹ laaye lọwọ awọn ajinigbe.