Awọn akẹkọọ Fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ ṣewọde lọfiisi gomina Ogun, tori alaga wọn ti wọn ji gbe

Faith Adebọla, Eko

Pitimu lawọn akẹkọọ Yunifasiti Ọlabisi Ọnabanjọ to wa l’Agọ-Iwoye, nipinlẹ Ogun, ya bo ileejọba ipinlẹ ọhun to wa l’Oke-Mọsan, niluu Abẹokuta, lọjọ Ẹti, Furaidee yii, ti wọn si ṣewọde lati fi aidunnu wọn han latari alaga ẹgbẹ wọn, Samson Ajasa, ti wọn lawọn janduku ṣe akọlu si, ti wọn si ji i gbe.

Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ fasiti ọhun, Ọgbẹni Micheal Oluwabunmi Awoyẹmi, to ṣaaju awọn oluwọde naa lọ sọfiisi gomina ipinlẹ Ogun sọ pe igbesẹ naa pọn dandan tori ẹsun ti wọn fi kan Oludamọran pataki si gomina Dapọ Abiọdun, Ọgbẹni Azeez Adeyẹmi, ni pe oun lo wa nidii iṣẹlẹ yii, wọn ni tori ọrọ oṣelu si ni.

Ọkan-o-jọkan akọle lawọn akẹkọọ naa gbe dani, ti wọn si n kọrin ọtẹ, orin ibinu loriṣiiriṣii lati fi aidunnu wọn han, ti wọn si n ke sijọba ipinlẹ Ogun lati da sọrọ ọhun.

Lara akọle naa ka pe: “Ẹ gba wa, ọkan wa o balẹ lati kawe mọ,” “Aabo lo ṣe pataki ju oṣelu lọ,” “Ohunkohun ko gbọdọ ṣe Samson Ajasa,” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ba a ṣe gbọ, wọn ni ọrọ eto idibo alaga kansu to n bọ lọna nipinlẹ Ogun yii lo fa ija laarin Ọgbẹni Ajasa to jẹ alaga ẹgbẹ awọn akẹkọọ nipinlẹ Ogun, National Association of Nigerian Students, ẹka ti ipinlẹ Ogun, ati Oludamọran pataki si gomina lori ọrọ awọn akẹkọọ nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Adeyẹmi Azeez, wọn fẹsun kan Azeez poun lo lọọ ran awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun kan lati ṣakọlu si Ajasa, ti wọn si ji i gbe l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, ti wọn si tun ji ọkọ ayọkẹlẹ rẹ gbe lọ.

Ọkan ninu awọn akọwe agba to tẹti si awọn akẹkọọ naa nigba iwọde wọn ọhun rọ wọn lati fọwọ wọnu lori iṣẹlẹ yii, o si fi da wọn loju pe Gomina Dapọ Abiọdun yoo ṣiṣẹ lori aroye ati ẹdun ọkan wọn to ba ti gbọ nipa ẹ.

Leave a Reply