Awọn akẹkọọ funjọba Kaduna ni ọjọ meje lati ṣawari awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ mejidinlogun ti wọn ji gbe

Faith Adebọla

 Agbarijọ awọn ẹgbẹ Oke-Ọya, ẹka ti awọn akẹkọọ Kaduna (Coalition of Northern Groups, Kaduna State Students Wing), ti koro oju si bawọn agbebọn ṣe ya bo sẹkiteria ijọba ibilẹ Zaria, nipinlẹ Kaduna, lọjọ Aje, ọsẹ yii, ti wọn si ji awọn oṣiṣẹ mejidinlogun gbe. Wọn waa lawọn fun ijọba ipinlẹ Kaduna ni gbedeke ọjọ meje lati gba awọn oṣiṣẹ kansu naa kuro lakata awọn ajinigbe, wọn lawọn maa bẹrẹ ifẹhonu han to lagbara gidi tijọba o ba ṣe bẹẹ.

Awọn akẹkọọ naa ni ọpọ lara awọn oṣiṣẹ ti wọn ji gbe yii ni wọn jẹ obi to n ran ọmọ nileewe giga, iṣẹlẹ naa si tabuku si ijọba apapọ ati tipinlẹ Kaduna lori eto aabo to mẹhẹ fawọn oṣiṣẹ rẹ.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, Oluṣekokaari wọn, Ọgbẹni Jamilu Musa, sọ pe lẹyin ọjọ meje, tawọn o ba ri awọn oṣiṣẹ naa pe wọn pada wale, niṣe lawọn maa ti ilu Zaria pa, toloko o ni i le roko, olodo o si ni i le rodo.

Wọn fi kun un pe nnkan ijọniloju lo jẹ lati ri i pe pẹlu irọrun ati ominira lawọn janduku agbebọn fi n ṣiṣẹ laabi wọn lagbegbe naa lasiko yii ti ẹmi awọn ọmọ Naijiria wa ninu ewu gidi, ti awọn alaṣẹ o si jigiri, tabi ki wọn gbe igbesẹ akin lori iṣoro ọhun.

“A ṣakiyesi pe awọn kan lara awọn oṣiṣẹ kansu ti wọn ji gbe yii jẹ obinrin, ti wọn jẹ iya ọpọ awa akẹkọọ ta a ṣi n lọọ ileewe lawọn ileewe giga kaakiri.

‘‘A n fi asiko yii sọ pe o to gẹẹ bayii, awa ọdọ ati akẹkọọ agbegbe Oke-Ọya ko ni i maa jokoo fọwọ lẹran lori ọrọ awọn janduku agbebọn atawọn ajinigbe to n han wa leemọ yii, tori ẹmi awọn obi ati akẹkọọ ṣeyebiye, ki i ṣe nnkan yẹpẹrẹ rara.

‘‘Ti ijọba atawọn alaṣẹ ko ba gbe igbesẹ gunmọ lori iṣẹlẹ yii, ki wọn si ri i pe wọn gba awọn obi wa atawọn oṣiṣẹ kansu naa pada laaye laarin ọjọ meje sasiko yii, a maa ti gbogbo agbegbe Zaria pa titi tijọba fi maa ṣe ohun ta a fẹ ni.”

Bẹẹ latẹjade ọhun sọ.

Leave a Reply