Awọn akẹkọọ girama ti wọn n gbe inu ọgba ileewe funra wọn loyun

Monisọla Saka

Ọwọ awọn alaṣẹ ile iwe girama Federal Government College, Ijanikin, nipinlẹ Eko, ti tẹ awọn akẹkọọ wọn kan ti wọn n yọ kuro ninu ọgba ileewe naa, ti wọn yoo si lọọ gba yara sinu otẹẹli pẹlu awọn akẹkọọ-binrin ẹlẹgbẹ wọn.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ṣe ṣalaye, awọn akẹkọọ to jẹ pe inu ọgba ileewe ni wọn n gbe yii (boarder), ni wọn sọ pe wọn o ṣẹṣẹ maa fo fẹnsi pẹlu awọn obinrin wọn, ti wọn yoo si fi aimọye ọjọ wa nita ileewe. Awọn ọmọ ti wọn ka iwa palapala mọ lọwọ yii lọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrinla si mẹtadinlogun.

Fun bii odidi saa eto ẹkọ mẹta ati taamu ti wọn ṣẹṣẹ pari yii, ni wọn lawọn akẹkọọ-kunrin bii meje atawọn obinrin marun-un fi n rapala jade ninu ayika ileewe wọn tẹnikẹni ko si mọ.

Aṣiri iwa agabagebe awọn ọmọ yii tu sọwọ awọn alaṣẹ ileewe nigba ti ọkan ninu awọn akẹkọọ-binrin naa loyun fun ẹlẹgbẹ rẹ lọkunrin.

Ẹnikan to sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ti ko fẹẹ darukọ ara rẹ sọ pe oju awọn ọmọ ọhun ti rita debii pe wọn maa n lo awọn egboogi oloro to lagbara bii codeine, molly ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti pupọ awọn obinrin wọn si tun maa n ba ọkunrin meji, mẹta lajọṣepọ lẹẹkan naa.

“Ohun to daju ni pe awọn kan ninu awọn oṣiṣẹ ileewe naa maa mọ si gbogbo iwa buburu tawọn ọmọ yii n hu, nitori bawo lọmọ ileewe girama ṣe maa kuro layiika ile-ẹkọ fun aimọye ọjọ tẹnikẹni o si ni i ṣakiyesi. Dajudaju, pupọ ninu awọn ọga ileewe naa n ri jẹ lọna kan tabi omi-in ninu nnkan tawọn ọmọ yẹn n ṣe ni”.

Awọn alaṣẹ ileewe naa lawọn obi di ẹbi ọrọ naa ru nitori iwa aibikita atọwọ yẹpẹrẹ ti wọn ni wọn fi mu awọn ọmọ awọn.

Nigba ti wọn n naka aleebu sawọn ọga ileewe pe wọn n gbero lati ṣe ọrọ naa ni oku oru, ọkan ninu awọn obi awọn ọmọ ileewe naa to pe orukọ ara ẹ ni Alex ni, “Eleyii waye nitori iwa ko kan mi ti ọga agba ileewe atawọn alamoojuto ilegbee awọn akẹkọọ-binrin ati ọkunrin nileewe naa n hu. Ti wọn ba fi le daṣọ bo iru ọrọ yii, awọn ọmọ mi wa nibẹ, awọn naa le pada lugbadi iru iṣẹlẹ bayii to ba ya”.

Ọgbẹni Johnson Smith, toun naa sọrọ koro oju sawọn ọga ileewe naa gẹgẹ bi wọn ṣe kuna lati daabo bo awọn ọmọ ti wọn wa labẹ amojuto wọn. O ni, “Awọn alaṣẹ gbọdọ mura si akitiyan wọn lati yọ kanda inu irẹsi awọn akẹkọọ naa kuro, nitori awọn ọmọ ti iwa ibajẹ ti gogo si wọn lara yii yoo pada ko ba awọn ọmọ wa naa. Wọn gbọdọ wa nnkan ṣe si i ni kiakia ni”.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga ẹgbẹ awọn obi ati olukọ ileewe naa, Oluṣọla Tokede, ṣalaye pe loootọ lawọn ọmọ kan sa kuro ninu ileewe, o ni ko si ohun to jọ pe awọn fẹẹ dọwọ bo ọrọ naa mọlẹ.

O fi kun un pe ẹẹmeji ọtọọtọ lawọn alaṣẹ ile-ẹkọ naa ti funra wọn gba awọn akẹkọọ naa mu nile itura lẹyin ti wọn ko ri wọn lọgba ile-ẹkọ. Nigba ti wọn le awọn kan kuro nileewe patapata, wọn fun awọn kan niwee lati gbe ile wọn fungba diẹ.

Ọgbẹni Tokede tun tẹsiwaju pe, lojuna ati ka awọn ọmọ ọhun lọwọ ko, awọn alaṣẹ ileewe naa tun gba awọn ọdẹ ibilẹ adugbo lati ri i daju pe gbogbo ayika naa ni wọn n ba awọn mojuto.

O ni, “Awa la kuku fọrọ naa to awọn obi leti lori ẹrọ ayelujara Whatsapp. O wa n ya mi lẹnu bayii bawọn obi kan ṣe waa fẹẹ sọrọ naa di ba-mi-in, nigba ti wọn n sọ pe a o ṣe nnkan kan nipa ẹ. Nigba tawọn obi ba kọ lati tọ awọn ọmọ wọn, o di dandan ki wọn ko iwa ibajẹ wọn ran awọn ọmọ yooku. Nigba tawọn ọmọ tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹẹdogun(15) si mẹrindinlogun (16) ba n ni owo to to miliọnu kan Naira ninu apo banki wọn, ti obinrin meji n ba ọkunrin kan lo pọ lẹẹkan naa. Wọn kuku ka wọn mu ni saa eto ẹkọ to kọja lọ naa. Ọmọ ọdun marundinlogun ti ko yẹ ko ti i mọ nnkan kan to ti waa jingiri ninu iwa ibajẹ. Iwa ibajẹ yii ti wa lara wọn wa lati ile wọn, nitori bẹẹ la si ṣe n ṣiṣẹ karakara lati ma ṣe gba wọn laaye ki wọn ko ba awọn to ku.

“A ti le awọn akẹkọọ ti wọn funra wọn loyun kuro nileewe, bẹẹ la fi gbele-ẹ fungba diẹ fa awọn ti wọn jọ n rinrinkurin leti, ṣugbọn wọn lanfaani lati waa ṣe idanwo ti asiko ba to”.

Leave a Reply