Stephen Ajagbe, Ilorin
Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii pe ki gbogbo awọn akẹkọọ nileewe giga to wa nipinlẹ naa pada sẹnu ẹkọ wọn lọjọ kọkanla, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ki wọn si tẹle gbogbo ilana ati ofin to wa nilẹ fun idena itankalẹ arun Korona.
Atẹjade ti akọwe iroyin lọfiisi gomina, to tun jẹ Alukoro igbimọ Covid-19, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, gbe sita ni ijọba ti paṣẹ fun gbogbo ileewe giga lati ṣeto bi wọn ṣe le dena arun naa, ati bi awọn akẹkọọ yoo ṣe mu ofin Covid-19 lo lasiko ti wọn ba wa nileewe.
O ni o ti di dandan fun gbogbo akẹkọọ lati lo ibomu ninu ọgba ileewe ati yara ikẹkọọ.
Wọn ni awọn alaṣẹ ileewe ko gbọdọ gba akẹkọọ kankan ti ko ba lo ibomu laaye lati wọ inu ọgba tabi ibikibi ninu ileewe wọn.
Bakan naa ẹwẹ, ijọba ti ya ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, sọtọ fun awọn akẹkọọ alakọọbẹrẹ ati girama lati wọle pada. O ni bi nnkan ba tun yipada lori arun Korona nikan ni ayipada le waye lori ọjọ iwọle naa.
Wọn waa rọ gbogbo araalu lati fọwọsowọpọ nipa titẹle ofin Covid-19 ati ọna lati dena rẹ.