Awọn akẹkọọ ileewe Kaduna ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ lawọn ko wẹ fun odidi oṣu meji

“Awọn agbebọn wọnyi nilo adura gidi, adura nikan ni ka maa gba ki Ọlọrun fọwọ tọ ọkan wọn. Ni temi, mo ti dariji wọn fun ohun ti wọn foju wa ri o, ṣugbọn mi o le gbagbe laye mi. Bii igba teeyan wa ni ọrun apaadi ni. Koda mi o gbadura ẹ fu ọta mi.”

Ọrọ yii ni Zakariya Magaji, ọkan lara awọn akẹkọọ-binrin to wa lara awọn mẹtadinlọgbọn ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ kuro lahaamọ awọn agbebọn to ji wọn gbe nileewe wọn nipinlẹ Kaduna sọ. Nigba ti wọn bi i pe bawo lọhun ṣe ri, niṣe lọmọbinrin naa bu sẹkun gbarada, o loun o mọ pe oun tun le foju oun ri awọn obi oun mọ laye.

Ṣe, ọjọ mẹrindinlọgọta gbako (oṣu meji o din diẹ) lawọn ọmọde wọnyi fi wa ni bebe iku, tawọn agbebọn naa n foju wọn rare, ti wọn si n fi oriṣiiriṣii iya jẹ wọn. Nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun yii, lawọn janduku agbebọn naa ya bo ọgba ileewe wọn, Federal College of Forestry and Mechanisation, to wa lagbegbe Afaka, niluu Kaduna, ti wọn si ji akẹkọọ mọkandinlogoji (39) lọ, lọkunrin lobinrin. Meji ninu wọn raaye sa mọ wọn lọwọ, awọn agbebọn naa kọkọ da awọn marun-un silẹ lẹyin ọjọ diẹ, wọn si tun fawọn marun-un mi-in silẹ lẹyin naa, lo ba ku awọn mẹtadinlọgbọn ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu karun-un, ta a wa yii.

Iku ti o ba paayan, to ba ṣi ni ni fila, o tọpẹ lọrọ awọn ọmọ ọhun. Niṣe ni omije n pe omije ran niṣẹ nigba tawọn akẹkọọ naa n royin ohun toju wọn ri fawọn obi wọn, awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn oniroyin ninu ọgba ileewe wọn ti wọn da wọn pada si lẹyin ti wọn ti kọkọ lọọ gba itọju pajawiri ni ọsibitu ijọba. Akẹkọọ-binrin kan, Sarah Sunday, sọ pe iya buruku lawọn jẹ ninu aginju ti wọn ko awọn lọ ọhun, wọn febi pa awọn, awọn si rin irin arin-wọdii, oriṣiiriṣii nnkan lawọn foju wina ẹ. O ni ko sẹni to fomi kan ara ninu awọn ni gbogbo asiko naa.

“Wọn n bu wa, wọn lu wa, ṣugbọn a dupẹ pe wọn o fibalopọ lọ wa. Ọjọ akọkọ ta a debẹ ni wọn ti lu wa ni kumọ, ti wọn si ṣe fidio bi wọn ṣe n lu wa.”

Sarah tun ṣalaye siwaju si i pe: “Awọn bọisi aarin wa ni wọn maa n lọọ pọn omi wa ka le fi gbọnjẹ. Tuwo pẹlu miyan kuka (ọbẹ ila) la n jẹ ju. Ẹẹkan ṣoṣo pere ni wọn se irẹsi fun wa, a si jẹ spaghetti lẹẹkan pẹlu”

Nigba ti wọn beere boya awọn ajinigbe naa maa n fi wọn silẹ lati lọọ ṣe opureṣọn mi-in, Sarah ni ‘bẹẹ ni, ṣugbọn wọn maa fi awọn kan lara ẹṣọ wọn ti wa, ko sigba ti wọn fi awa nikan silẹ patapata. Koda, ti awọn ọkunrin aarin wa ba fẹẹ lọọ pọnmi, awọn agbebọn kan maa fibọn AK-47 sin wọn lọ sin wọn pada ni.

‘Yatọ si pe a ko ri omi wẹ, gbangba ita la maa n wa ninu ojo, ninu oorun. Wọn kọ ahere jakujaku kan sibẹ, ṣugbọn ko si bi ojo o ṣe ni i pa wa labẹ ahere naa, gbalasa ita naa la n sun lalẹ.”

Akẹkọọ-binrin mi-in, Pamela Ibrahim ni awọn janduku agbebọn naa sọ fawọn pe ijọba lawọn n ba ja, ki i ṣe awọn obi wa, awọn si ti pinnu lati han ipinlẹ Kaduna leemọ.

“Ki wọn too tu wa silẹ, awọn ajinigbe naa sọ fun wa pe awọn o ni nnkan kan lodi si wa (awa akẹkọọ) o. Wọn nitori awọn fẹ kijọba waa sẹtuu (settle) awọn lawọn ṣe ji wa gbe, ati pe awọn naa fẹẹ kawe kawọn niṣẹ gidi lọwọ, kawọn si nile lori bii tawọn ọmọ Naijiria yooku, tijọba o ba si ṣe nnkan tawọn fẹ, awọn maa maa yọ Kaduna lẹnu ni. Ede Fulani ati Hausa ni wọn n sọ pọn-ọn-ran-pọn.

Pamẹla ni ẹnikan wa to dagba daadaa laarin awọn agbebọn naa, baba yii ni ki i jẹ ki wọn fọwọ kan wa tabi ba wa ṣeṣekuṣe. Ti wọn ba ti ri i pe baba yii o si nitosi, niṣe ni wọn maa n lu wa, wọn a si maa ṣepe fun wa.

Yoruba bọ, wọn ni ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni sọnu lọ, bawọn akẹkọọ yii ṣe n fomije sọ ipo ti wọn ba ara wọn lọdọ awọn ajinigbe yii, bẹẹ ni nnkan naa ko rọgbọ fawọn obi wọn ti wọn ṣadeede wa ọmọ wọn ti, ti wọn si mọ pe ohunkohun lo le ṣẹlẹ si wọn.

Ọkan lara awọn obi naa, Ọgbẹni Ibrahim Hassan ni inu oun dun gan-an, oun si dupẹ lọwọ Allah pe oun tun foju ri ọmọ oun laaye, o ni ẹgbọn ẹ ti dajọ igbeyawo sọna ki iṣẹlẹ buruku naa to ṣẹlẹ. “Ọkan mi poruuru gidi ni, mi o mọ eyi to kan fun mi lati ṣe. Ṣe ki n fi odidi ọmọ silẹ ki n maa ṣayẹyẹ igbeyawo ni, abi ki n ba ayẹyẹ igbeyawo ta a ti dajọ ẹ sọna jẹ ni. Ọlọrun ni mo kan n ke pe lojoojumọ, aye su mi patapata.

“Ohun to tiẹ waa fọ gbogbo ẹ loju ni igba ti a gbọ pe wọn ti pa awọn kan lara awọn akẹkọọ Fasiti Greenfield ti wọn ji gbe lẹyin ti awọn ọmọ wa yii, ha, mo ni boya ni mo tun maa le foju kan ọmọ mi mọ o, omije bo mi, mo sunkun bii ọmọde ni, o ju ki wọn na mi lẹgba lọ.

Ọla (Satide) yii ni igbeyawo ẹgbọn ẹ ni Zaria, ẹ o ri i pe ayọ mi di meji ni bayii.

Ni ti Ọgbẹni Friday Sanni, meji lawọn ọmọ ẹ to n kẹkọọ nileewe naa, awọn mejeeji si ni wọn ji ko, ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ yii. O ni ni toun o, afi toun ba ri i pe aabo to peye ti wa fawọn akẹkọọ naa nikan loun maa too gba kawọn ọmọ oun pada kawe nibẹ.

Leave a Reply