Awọn akẹkọọ meji padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ lọna Ilọrin si Ogbomọṣọ

Stephen Ajagbe, Ilorin

Akẹkọọ ipele akọkọ to wa lọ́dún keji, JSS 2 meji ni wọn padanu ẹmi wọn, tawọn marun-un mi-in si fara pa ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lọna Ilọrin si Ogbomọṣọ l’Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni nnkan bii aago meji ọsan, lagbegbe Gaa Odota, nidojukọ ile-itaja epo bẹntiroolu Alade.

Nibi ti awọn akẹkọọ to doloogbe naa duro si ni awakọ ero kan to ji ero gbe lai gba iwe aṣẹ ti lọọ ya ba wọn, to si run wọn pa loju ẹsẹ.

Lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ọkọ tipa to ko iyanrin kan to n sa ere buruku lo lọọ ya ba ọkọ ero naa, nibi tiyẹn si ti n pẹwọ fun ọkọ akoyanrin ọhun lo ti tun kọlu ọkọ meji ati kẹkẹ Maruwa kan.

Ọga agba ileeṣẹ to n ri si igboke-gbodo ọkọ loju popo, FRSC, ẹka ipinlẹ Kwara, Jonathan Ọwọade, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa ṣalaye pe ere asapajude lo fa ijamba ọhun.

Ọwọade ni lapapọ, eeyan mẹsan-an lo fara gba ijamba naa. O ni mọlẹbi awọn meji to ku ti waa gbe oku wọn.

Ileewosan Geri Alimi to wa nitosi agbegbe tijamba naa ti ṣẹlẹ ni wọn ko awọn to fara pa lọ lati gba itọju.

Leave a Reply