Faith Adebọla
Akolo awọn ẹṣọ NDLEA, ileeṣẹ to n gbogun ti awọn to n lo egboogi oloro tabi ti wọn n ṣowo rẹ ni Modupẹ Angel Babalọla ati ẹlẹgbẹ ẹ, Sonia Esekhagbe, wa ba a ṣe n sọ yii. Akẹkọọ ileewe poli ni wọn, ṣugbọn ibi ti wọn ti n lo egboogi oloro, ti wọn tun n ṣowo rẹ ni wọn ka wọn mọ ti wọn fi mu wọn.
Alukoro fun ileeṣẹ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, ṣalaye pe ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an yii, lọwọ NDLEA ba awọn afurasi ọdaran mejeeji ọhun niluu Benin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Edo.
O niwadii fihan pe akẹkọọ ileewe gbogboniṣe, iyẹn Edo State Polytechnic, to wa niluu Uzen, nipinlẹ Edo, lawọn ọmọ ọhun, ẹni ọdun mọkanlelogun ni Modupẹ Babalọla, nigba ti Sonia jẹ ẹni ogun ọdun.
Egboogi oloro kan ti wọn n pe ni skunk ni wọn ka mọ wọn lọwọ, idi mọkanlelogun (21) ti wọn fẹẹ lọọ ta lawọn agbofinro naa gba lọwọ wọn.
Babafẹmi lawọn ọmọbinrin naa jẹwọ pe loootọ lawọn n fa egboogi oloro naa, awọn si n ṣowo rẹ, wọn lowo tawọn n pa nidii okoowo buruku yii lawọn fi n ran ara awọn nileewe.
Babafẹmi lawọn ọmọbinrin yii tun n ṣiṣẹ aṣẹwo pẹlu, ṣugbọn ni bayii, wọn ti wa lọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ba iṣẹ iwadii lọ nipa wọn.