Awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe royin: Omi tawọn maaluu n mu ni wọn fun wa mu, ojoojumọ la n jẹ kumọ

Faith Adebọla

Yoruba bọ, wọn ni, ‘aja to ba re’le ẹkun to bọ, niṣe lo yẹ ka ki i ku ewu’. Bọrọ awọn ọmọleewe ijọba Government Science College, to wa ni Kagara, nipinlẹ Niger, ti wọn ṣẹṣẹ bọ kuro lahaamọ awọn agbebọn lọjọ Abamẹta, Satide yii, ṣe ri gẹlẹ niyi, wọn loju awọn ri mabo ninu igbo ti wọn ji wọn gbe si.

Ọjọ mẹsan-an gbako lawọn ọmọleewe naa fi wa lakata awọn ọdaran agbebọn naa, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji yii, lawọn janduku agbebọn naa ya bo ilegbee (hostel) awọn ọmọ yii ninu ọgba ileewe wọn, wọn yinbọn pa ọkan lara awọn ọmọ naa, wọn ji mejidinlọgbọn lara wọn gbe, wọn tun ji awọn tiṣa wọn mẹrin, ati mọlẹbi awọn tiṣa naa mẹfa. Aropọ gbogbo wọn jẹ mejidinlogoji ti wọn tu silẹ lọjọ Satide.

Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani Bello lo kọkọ royin ohun toju awọn ọmọ naa ri nigba ti wọn n dari bọ wale, o ni irin a-rin-wọ-dii lawọn majeṣin yii rin ninu igbo kijikiji fun wakati mẹjọ, lati aago mẹrin idaji ti wọn ti yọnda wọn, ki wọn too rin jade si gbangba.

O lawọn oniṣẹ ọba ti wọn lọọ pade wọn sọ foun pe omi tun fẹẹ tẹyin wọ’gbin lẹnu, latari bawọn ẹgbẹ agbebọn mi-in tun ṣe rẹburu awọn ọmọ naa lọna, ti wọn lawọn o ni i jẹ ki wọn lọ, afi tawọn ba rowo. Gomina ko sọ boya wọn fun wọn lowo ati iye ti wọn gba, ṣugbọn o ni wọn da wọn gunlẹ fungba diẹ, ẹbẹ si pọ gidi ki wọn too yọnda wọn lati maa lọ.

Ṣugbọn kekere leyi jẹ lara ohun tawọn ọmọ naa royin pe oju awọn ri ninu aginju ti wọn ko wọn pamọ si.

Ọkan lara wọn, Abubakar Sidi, to wa nipele ẹkọ SS3, sọ pe niṣe ni wọn to awọn bii ẹni to sori ila, ti wọn si n fun awọn lẹgba lọkọọkan kari-kari. O ni kumọ kan bayii ni wọn fi n lu awọn, ojoojumọ si ni.

O ni ẹwa ni wọn n se fawọn jẹ, ẹwa nikan ni, ẹẹkan lojumọ si lawọn n jẹun, o lẹwa ọhun ko ni i jinna nigba mi-in, ṣugbọn ko sẹni to le sọrọ laarin awọn, tori wọn ti sọ fawọn pe ẹni to ba ṣaroye maa fiku ṣefa jẹ ni.

O lomi o si ninu igbo naa, awọn o tiẹ mọ ibi ti wọn ti lọọ wa omi wa, omi rukuruku kan ti wọn bu kalẹ fawọn maaluu ninu basia kan ti wọn gbe sibẹ lawọn maa n bu mu. O lawọn ni wọn maa bu omi naa fawọn, ẹẹkan lojumọ naa si ni. O loriṣiiriṣii iya bayii ni wọn fi jẹ awọn.

Ọmọ SS3 mi-in, Suleiman Lawal, sọ pe awọn jiya mọ pọnmọ-pọnmọ ete lọdọ awọn agbebọn ọhun, o ni lilu buruku buruku ni wọn fi tawọn ṣe, kumọ ti wọn fi n lu awọn maaluu ni wọn fi n lu awọn. O ni wọn o bikita bawọn ba ku.

“Iya gidi ni wọn fi jẹ wa o, mi o ri iru nnkan bayii ri laye mi, wọn mu wa rin bii ẹṣin ni, a kan n rin ọna jinjin lai mọ ibi ti a n lọ, irin ojoojumọ lati ibi kan si ibi kan ni, ninu igbo. Ko rọrun rara.

Ọrọ naa ka akẹkọọ-binrin Sarat Isah lara debii pe ko sọ ju gbolohun meji lọ to fi bu sẹkun. O ni o dun oun gan-an, iya toun ko jẹ ri laye ni wọn fi jẹ oun. O ni niṣe ni wọn ṣe awọn bii ọmọ ẹran.

Ohun toju awọn ogo-wẹẹrẹ yii ri buru debii pe niṣe ni ọkan ninu wọn bẹrẹ si i seeemi nigba ti wọn fi ko wọn jade. Gomina Abubakar lawọn ti sare gbe ọmọ naa lọ sileewosan ijọba ki wọn le doola ẹmi ẹ. O lawọn tun ti pese itọju pajawiri ati ayẹwo iṣegun fun gbogbo wọn. Ọkunrin naa ni akata ijọba lawọn ọmọ naa ṣi maa wa fọjọ meji si mẹta kan, ti wọn ba ti ri i pe ara wọn ti balẹ, ilera wọn si ti sunwọn lawọn maa da wọn pada fawọn obi wọn.

Ọmọ SS2 kan, Mahmood Mohammed, sọ pe oun o le sọ boya oun tun maa pada sileewe. O lọwọ awọn obi oun niyẹn wa, ṣugbọn iya ti wọn fi jẹ awọn yii ko mu kileewe wu oun lati lọ mọ.

Iṣẹlẹ yii, atawọn mi-in to tun waye lẹyin eyi lagbegbe naa ti ko ipaya bawọn obi pẹlu, ọpọ wọn lo sọ fawọn oniroyin pe awọn o le yọnda ọmọ wọn lati lọ sileewe ti ko si aabo mọ.

Abilekọ Hafsat Abdullahi sọ pe meji lara awọn ọmọ oun lo kagbako iṣẹlẹ yii, o dupẹ lọwọ Ọlọrun pe wọn ti pada. O loun ati baba wọn ti pinnu pe tawọn ba tiẹ maa fi ọmọ sileewe ijọba, awọn ko ni i yọnda ki wọn maa gbe inu ọgba ileewe mọ, ki wọn maa lọ, ki wọn si ma pada lojumọ ni.

Bẹẹ lawọn obi mi-in kọminu gidi lori iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply