Awọn akẹkọọ yoo wọle lọjọ Aje l’Ọṣun, Eko ati Ogun

Florence Babaṣọla, Adefunkẹ Adebiyi

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn akẹkọọ kaakiri ipinlẹ naa yoo pada sẹnu ẹkọ wọn.

Oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ eto ẹkọ, Ọnarebu Jamiu Ọlawumi, lo sọ eleyii di mimọ. O ni ijọba ti ṣe gbogbo eto lati ri i pe iwọle awọn akẹkọọ naa ṣee ṣe lọla.

O ni yatọ si oniruuru eto tijọba ti ṣe sileewe kọọkan lọdun to kọja lati gbogun ti itankalẹ arun Korona, ọpọlọpọ nnkan idaabobo nijọba tun ti ko fun awọn ileewe alakọọbẹrẹ atileewe girama.

Ọlawumi fi ọkan awọn obi ati alagbatọ balẹ pe oniruuru ipade nijọba ti ṣe pẹlu awọn olukọ, o si rọrun fun awọn akẹkọọ lati tẹle ilana naa ni kete tawọn olukọ ba ti sọ fun wọn.

O ni o rọrun lati kawọ itankalẹ ajakalẹ Korona laarin awọn ọmọleewe, yatọ si bo ṣe maa n ri lawọn ibudo bii ọja atibi ayẹyẹ.

O wa ke si awọn olukọ lati ri i pe wọn fi ẹsẹ ofin ati ilana ijọba mulẹ laarin awọn akẹkọọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ Ogun ti kede pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ni awọn akẹkọọ ileewe alakọọbẹrẹ, girama ati ileewe giga yoo wọle pada fun saa eto ẹkọ ti wọn bẹrẹ lọdun to kọja.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, fi sita lo ti sọ pe ki gbogbo akẹkọọ wọle lọjọ Mọnde naa.

Ṣugbọn wọn ni gbogbo ofin to de Korona ni wọn gbọdọ tẹle, bii fifọ ọwọ deede pẹlu ọṣẹ atomi, ati fifi oogun apakokoro fọwọ. Wọn si gbọdọ maa lo ibomu pẹlu.

Ko gbọdọ si ipejọpọ ti wọn fi n to sori ila laaarọ, bẹẹ ni ko saaye a n fun pọ mọra ẹni. Wọn ni ki yara itọju ati iyasọtọ tawọn ileewe yii ti pese silẹ maa ṣiṣẹ bo ṣe yẹ, ki awọn ohun ti wọn nilo fun itọju si wa nibẹ digbi.

Ọrọ ko fi bẹẹ yatọ nipinlẹ Eko pẹlu bi ijọba ṣe kede pe ki awọn akẹkọọ nipinlẹ naa pada sileewe. Bẹẹ lo rọ awọn olukọ lati ri i pe wọn pa ofin Korona ti ijọba ti la kalẹ mọ. Ki wọn ri i pe awọn akẹkọọ n lo ibomu, wọn si n ya ara wọn sọtọ, bẹẹ ni ki wọn maa fọ ọwọ wọn loorekoore.

Leave a Reply