Awọn akẹkọọ yunifasiti lu Oluṣọla to ja wọn lole pa l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọmọkunrin kan, Sunday Oluṣọla, ku iku ojiji l’Ọjọruu, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa yii, lasiko to wọle awọn akẹkọọ yunifasiti ipinlẹ Ekiti kan jale, ti wọn ka a mọbẹ, ti wọn si lu u titi to fi ku.

Iworoko-Ekiti ni yunifasiti naa wa, nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ọjọ naa ni Oluṣọla ati ọrẹ rẹ kan dihamọra ogun pẹlu ibọn atawọn nnkan ọṣẹ mi-in, ti wọn wọle awọn ọmọ yunifasiti ọhun, wọn si ti ja wọn lole awọn ẹru bii kọmputa, foonu ati owo, ko too di pe awọn ti wọn ja lole figbe ta, ti awọn yooku wọn si rọ debẹ, ti wọn gba ibọn lọwọ Oluṣọla ati ikeji rẹ, ṣugbọn ọrẹ rẹ naa pada sa lọ.

Ọkan ninu awọn ọmọ yunifasiti naa to ba akọroyin wa sọrọ ṣalaye pe awọn akẹkọọ lo pọ ju ninu awọn olugbe adugbo Osekita tawọn ole naa ti waa jale, ohun to jẹ ki wọn ya wọbẹ lati gba awọn ẹgbẹ wọn silẹ lọwọ awọn ole naa niyẹn.

O ni bi wọn ṣe gba agbara lọwọ awọn ole naa ni wọn bẹrẹ si i lu Oluṣọla tọwọ ba, wọn si lu u titi ti ẹmi fi bọ lẹnu ẹ. Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

O ni oku ole naa lawọn ba lọwọ awọn akẹkọọ yii. Wọn tilẹ ti fẹẹ dana sun un bo ṣe wi, awọn ọlọpaa lo gba a lọwọ wọn ti wọn ko fi sọ taya si oku rẹ lọrun, ki wọn si ṣana si i.

Abutu naa fidi ẹ mulẹ pe ole ni Oluṣọla ti wọn lu pa yii n ja, o ni ni nnkan bii oṣu mẹfa sẹyin lọwọ ọlọpaa tẹ ẹ fẹsun ole jija, o si jẹwọ fawọn nigba naa pe oun atawọn ọrẹ oun meji, Tochukwu ati Tọmiwa, lawọn jọ n jale kiri.

Ṣa, wọn ti gbe oku ole to doloogbe yii sile igbokuu-pamọ lọsibitu ijọba ipinlẹ Ekiti. Awọn nnkan ọṣẹ tawọn ọlọpaa ba lara rẹ ni ibọn ṣakabula meji, ada nla meji, aṣọ iboju atawọn irinṣẹ iṣẹ okunkun mi-in.

 

 

Leave a Reply