Awọn alaṣẹ fẹẹ ṣewadii b’awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe yinbọn mọra wọn ni Poli Ibadan 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Igbimọ alaṣẹ ileewe Gbogboniṣe Poli Ibadan (The Polytechnic, Ibadan), ti pinnu lati ṣewadii rukerudo to ṣẹlẹ ninu ọgba ile-ẹkọ giga naa.

Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lọrọ di bo-o-lọ-o-yago-lọna nigba tawọn ẹruuku ṣina ibọn bolẹ funra wọn ninu ọgba ile-ẹkọ naa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, oriṣii ikọ ẹgbẹ okunkun meji kan ni wọn fìja pẹẹta lasiko naa ti wọn fi n yinbọn mọra wọn loju mọmọ bii igba ti wọn wa loju ogun.

Awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ Poli Ibadan bẹrẹ si i fi ipe ati atẹranṣẹ kilọ fawọn eeyan wọn pe bi wọn ba ni nnkan kan-an ṣe ninu Poli ati agbegbe ẹ, ki wọn jọọ, tun ero wọn pa nitori  ibọn ni wọn n yin para wọn lọwọ nibẹ bayii bayii.

Iroyin yii lo mu ki inu ọgba poli naa da paroparo titi ti ilẹ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, fi ṣu, nitori awọn ọkọ ero to n na inu ibẹ ko lọ gbe ero lọ tabi gbero jade ninu ọgba naa. Bẹẹ lawọn afẹnifẹre n da awọn ọkọ aladaani to ba fẹẹ gba ibẹ kọja pada pe ki wọn ma lọọ fori la iku.

Nigba to n fìdi iroyin yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ile-ẹkọ Poli Ibadan, Alhaji Ṣọladoye Adewọle, sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, ṣugbọn ko sẹni to ku, tabi fara pa nibẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Loootọ lo ṣẹlẹ pe wọn yinbọn ninu ọgba yii, ṣugbọn ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ yẹn rin, bẹẹ ni ko ṣẹni to fara pa. Gbogbo iṣẹlẹ yẹn ko si ju iṣẹju marun-un lọ.

“Igbimọ alaṣẹ ile-ẹkọ yii ti pinnu lati ṣewadii ohun ti ṣokunfa iṣẹlẹ naa ki wọn le fi iya to ba tọ jẹ ẹni ti aje iṣẹlẹ yẹn ba ṣi mọ lori”

Leave a Reply