Awọn alaṣẹ Kwara Poli le akẹkọọ mẹrin to jiwee wo lasiko idanwo danu 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Nitori pe wọn jiwee wo lasiko idanwo, awọn alaṣẹ ileewe giga Kwara State Polytechnic, Ilọrin, ti le akẹkọọ mẹrin danu, wọn ni kawọn mẹfa miiran lọọ lo saa kan nile.

Ninu atẹjade kan ti awọn alasẹ ileewe naa fi síta l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, niluu Ilọrin, ni wọn ti ṣọ pe awọn ti le akẹkọọ mẹrin danu patapata, tawọn si tun le awọn mẹfa miiran pada sọdọ obi wọn fun saa kan gbako, fẹsun pe wọn gbe iwe wọle, atawọn iwa miiran to fara pẹ ẹ lasiko ti wọn n ṣe idanwo lọwọ ni saa to kọja. Iwa yii ni wọn lo ta ko ofin ileewe ọhun gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ilewọ ti ileewe naa fun wọn nigba ti wọn wọle, ti iwe naa si kun fun oniruuru ofin

Orukọ ati nọmba igbaniwọle awọn akẹkọọ mẹfa ti wọn ni ki wọn lọọ sinmi nile fun saa kan ni: Alabi Lukman Damilare (ND/19/CEC/FT/199) lati ẹka imọ ẹrọ (Civil Engineering), Abdullateef Abiodun Ismail (ND19/COM/FT/601), lati ẹka imọ kọmputa (Computer Science), Abdullateef Saheed Damola (ND/19/COM/FT/491), imọ kọmputa, Shodiq Ayuba Ayinde, imọ kọmputa (HND/19/EEE/FT/177) ẹka imọ nipa ina mọnamọna (Elect/Elect) Okesanjo Nafiu Kanyinsọla (ND/18/AET/FT/023), imọ nipa eto ọgbin ati imọ ẹrọ nipa ayika (Agricultural and Bio-Environmental Engineering), Yakub Wasilat Ọpẹyẹmi (ND/19/ABE/FT/054), ni ẹka yii kan naa.

Awọn akẹkọọ mẹrin ti wọn le danu patapata ni:

Salami Ridwan Ọlalekan (ND/17/BAM/PT/410) lati ẹka okoowo (Business Administration), Agbabiaka Temidayọ Fausat (ND/19/PAD/FT/568), ẹka ẹkọ nipa aato ilu (Public Administration), Ndanusa Alimi Shaaba (HND/19/COM/FT/084), ẹka kọmputa (Computer Science) ati Adelodun Yusuf O. (ND/19/BF/FT/061), ẹkọ nipa eto ifowopamọ ati inawo (Banking and Finance). Awọn alasẹ ileewe naa ti waa gba wọn ni imọran pe ki wọn tẹle aṣẹ ileewe, naa ki wọn si takete si inu ọgba wọn.

 

Leave a Reply