Awọn alaṣẹ Poli Iree ni gbogbo akẹkọọ gbọdọ pa aṣẹ isede ilu naa mọ

Florence Babaṣọla, Ọṣogbo

Awọn alakooso ileewe gbogboniṣe ilu Iree ti kilọ fawọn akẹkọọ wọn lati pa aṣẹ isede (Curfew) ti adari ilu Iree pa mọ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe ileewe naa, J. A. Fadeji, fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe latari wahala ipaniṣowo to n ṣẹlẹ lojoojumọ niluu naa lo fa a ti wọn fi kede isede ọhun.

Fadeji sọ pe, “Igbimọ Aree pẹlu ifọwọsowọpọ awọn oṣiṣẹ alaabo niluu naa ti kede isede niluu Iree laarin aago mẹwaa alẹ si aago mẹfa aarọ.

“Eleyii ko ṣẹyin wahala iṣekupani, idigunjale, ijinigbe ati oniruuru iwa ibi to n ṣẹlẹ lojoojumọ ninu ilu naa.

“Nitori naa, gbogbo oṣiṣẹ ati awọn akẹkọọ wa ti wọn n gbe inu ilu Iree la rọ lati tẹle aṣẹ yii, ki wọn jokoo sinu ile wọn laarin asiko ti wọn kede naa fun anfaani ara wọn.

Leave a Reply