Awọn alaṣẹwo Eko naa n binu si SARS, wọn ni wọn n baṣẹ awọn jẹ

Aderounmu Kazeem

Bi awọn ọmọ orilẹ-ede yii kaakiri awọn ipinlẹ ṣe n fẹhonu han wi pe awọn ko fẹ ẹṣọ SARS mọ, awọn alaṣẹwo naa ti bọ sita loni-in, wọn lawọn naa korira wọn gidi.

Nibi iwọde kan to waye lagbegbe kan l’Ekoo ni awọn alaṣẹwo yii ti darapọ mọ awọn to n kigbe kiri wi pe, ijọba Buhari gbọdọ ko awọn ẹṣọ agbofinro to n gbogun ti iwa ọdaran atawọn iwa ibajẹ mi-in kuro nilẹ. Wọn sọ pe, niṣe ni wọn n faye ni ọmọ Naijiria lara, paapaa awọn ọdọ.

Awọn oniṣẹ nọbi yii sọ pe, ohun buruku lo maa jẹ ti ko ba si ọdọ kankan to n ṣiṣe yahoo mọ, iyẹn awọn ọdọlangba ti wọn n fi ẹrọ ayarabiiaṣa, intanẹẹti, lu awọn  eeyan ni jibiti, paapaa awọn ara oke-okun.

Wọn  ni awọn ọmọ Yahoo yii gan-an lo maa n sanwo gidi fawọn, ati pe bi awọn SARS ṣe maa n ko idaamu ba wọn yii, bii ẹni ba iṣẹ je fawọn ni, nitori kositọma daadaa ni awọn eeyan ọhun n ṣe.

Irukiru ọbẹ awọ, ọna ti iwọde SARS tun gba yọ lowurọ kutu oni niyẹn o.

 

Leave a Reply