Awọn alailaaanu ọmọ Naijiria kan lo fẹẹ doju ijọba mi de

Faith Adebọla

Aarẹ orileede yii, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti sọ pe o ṣi n ya oun lẹnu bawọn ọbayejẹ ẹda kan ṣe pinnu lati wo ijọba mọ oun lori, o ni awọn alailaaanu ọmọ Naijiria kan lo wa nidii ọrọ yii.

Buhari sọrọ yii nigba to n gba abajade ipade ẹlẹẹkẹfa ti igbimọ to n gba Aarẹ nimọran lori ọrọ-aje (Presidential Economic Advisory Council) eyi ti Ọjọgbọn Doyin Salami ṣe alaga rẹ lọjọ Abamẹta yii, nile ijọba, l’Abuja.

Buhari ni o jọ oun loju gidi pe gbogbo aṣẹ ati gbedeke ti ijọba apapọ ba gbe kalẹ lawọn kan ti pinnu lati ta ko. O ni pẹlu isapa ijọba oun lati ma ṣe jẹ ki ẹru ofin wọlu, leyi to mu kawọn tilẹkun awọn ẹnubode ilẹ wa fun eyi to ju ọdun kan lọ, sibẹ awọn ọmọ orileede yii kan ṣi wa gbogbo ọna alumọkọrọyi lati maa ṣe fayawọ awọn ọja ti ko bofin mu naa niṣo.

“Awọn eeyan kan ya ọdaju, wọn o laaanu orileede yii rara. A tilẹkun awọn ẹnubode wa lati din fayawọ epo rọbi, ibọn ati nnkan ija oloro, awọn ẹru ti ko bofin mu, ku. Ẹyin igba naa ni ọga agba ileeṣẹ kọsitọọmu pe mi pe awọn ti mu awọn tanka epo bẹntiroolu bii ogoji kan ti wọn n ṣe fayawọ epo rọbi wọlu. Mo ni ki wọn ta epo naa, ki wọn ta awọn tanka ọhun, ki wọn si ko owo ẹ sapo ijọba.

Laarin ẹ naa ni wọn n ko ibọn ati nnkan ija oloro wọle, ti wọn n fi ọkada ati mọto ko irẹsi wọlu.

“Mo paṣẹ pe ki wọn yinbọn pa ẹnikẹni ti wọn ba ri ibọn AK-47 lọwọ ẹ lai gbaṣẹ loju-ẹsẹ, sibẹ, kiko ibọn wọlu o dawọ duro. O yẹ kawọn eeyan le laaanu orileede wọn.”

Aarẹ Buhari tun sọ pe afi ta a ba pada sidii iṣẹ agbẹ la maa too le kapa ọrọ-aje to n ṣojojo lasiko yii. O ni ‘imọ ijinlẹ ti n gba agbara lọwọ epo rọbi, ṣugbọn Ọlọrun ba wa ṣe e ti a ni afẹfẹ gaasi lọpọ yanturu, a ni ilẹ ọlọraa to ṣee ṣọgbin, a o si ti i lo o debikan.”

Aarẹ Buhari ṣeleri pe ijọba apapọ maa tubọ gbaju mọ iṣe ọgbin ati ipese ounjẹ lọna igbalode lati le fun awọn araalu niṣiiri ki wọn pada sẹnu iṣẹ agbẹ.

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, lo gbẹnu Aarẹ sọrọ nibi ipade naa.

Leave a Reply