Awọn alakooso LCC sun ọjọ ti wọn yoo bẹrẹ si i gbowo ni toogeeti Lekki siwaju

Monisola Saka, Eko
Lẹyin ọpọlọpọ ijiroro pẹlu awọn lookọ lookọ, ileeṣẹ to n mojuto toogeeti to wa ni Lẹkki, ‘Lekki Concession Company Limited’ (LCC), ti sun ọjọ ti wọn yoo bẹre si i gbowo ni ori biriiji to so Lekki ati Ikoyi pọ siwaju, wọn ni awọn yoo maa kede rẹ laipẹ.
Adari ileeṣẹ naa, Yọmi Ọmọmuwasan sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to buwọ lu. O ni ileeṣẹ ọhun mọ-ọn-mọ sun ọjọ ti awọn yoo maa gbowo lori oju ọna yii siwaju ni lati le ba awọn tọrọ kan sọrọ ni Eti-Ọsa, agbegbe Lekki, ki wọn si yanju gbogbo ọrọ to n run nilẹ, ki awọn le ṣe ohun ti wọn n fẹ, ki igbesẹ ti awọn fẹẹ gbe le rọ tọtun-tosi lọrun.
O fi kun un pe sisun ọjọ naa siwaju yoo fun awọn eeyan laaye lati forukọ silẹ fun eto naa lori ẹrọ ayelujara.
“Gẹgẹ bii ileeṣẹ to daa, irọrun awọn eeyan agbegbe wa jẹ wa logun. Fun idi eyi, a fẹẹ tẹsiwaju lori ọrọ to wa nilẹ pẹlu awọn tọrọ kan”.
“A ti gbaradi lati bẹrẹ iṣẹ pada lori biriiji toogeeti, a si n dupẹ fun ifọwọsowọpọ awọn tọrọ kan, a ti sun ọjọ ti iṣẹ wa yoo bẹrẹ siwaju, eyi ti yoo fun awọn onibaara wa laaye lati forukọ silẹ fun ilo ẹrọ ẹlẹtroniiki, ki lilọ bibọ awọn eeyan le ma mu idiwọ dani”.
Igbesẹ tuntun yii waye lẹyin ọpọlọpọ ipade lọsẹ to kọja laarin awọn igbimọ ileeṣẹ LCC ati awọn eekan ilu, titi kan ẹgbẹ awọn to n gbe ni agbegbe ibẹ.
Gomina Babajide Sanwo-Olu wa ni ikalẹ lakooko ipade to jẹ akọkọ iru rẹ ọhun, lẹyin eyi ni LCC ati ẹgbẹ awọn araadugbo ibẹ pade lẹẹmeji ọtọọtọ. Ọrọ ṣi n lọ lọwọ laarin ileeṣẹ LCC ati awọn tọrọ kan, lẹyin ajọsọ yii ni wọn yoo fi ọjọ iwọle tuntun lede laipẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii, lo yẹ ki wọn bẹrẹ si i gbowo nibẹ gẹ bi ọn ṣe kede ṣaaju.
Ohun ti wọn sọ ni pe awọn yoo fun awọn eeyan to n gba oju ọna naa kọja lati lo o fun odidi ọjọ mẹẹẹdogun lai san kọbọ, ṣugbọn to ba ti di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii lawọn yoo bẹrẹ si i gbowo lori rẹ.
Ipade oriṣiiriṣii, ninu eyi ti kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Eko atawọn alaṣẹ ileeṣẹ naa pẹlu awọn olugbe agbegbe Lekki wa ni wọnṣe, nibi ti awọn eeyan naa ti yari mọ ijọba lọwọ pe awọn ko sanwo toogeeti yii mọ.
Lọjọ to yẹ ki wọn bẹrẹ si i gbowo naa, niṣe ni wọn ko awọn ọlọpaa si awọn agbegbe toogeeti naa ni imurasilẹ lati dena wahala to ṣee ṣe ko ṣẹlẹ bi awọn araadugbo naa ba kọ lati sanwo.
Ṣugbọn lojiji ni ijọba tun yi ipinnu wọn pada pe awọn ti sun ọjọ ti awọn yoo tun bẹrẹ si i gba owo naa siwaju, wọn ni awọn tun fẹẹ ba awọn tọrọ kan ṣepade, ki awọn si jọ ni asọyepo. Ṣugbọn awọn to mọ bọrọ ṣe n lọ sọ pe nitori eto idibo to n bọ ni wọn ṣe sun ọjọ eto naa siwaju, nitori wọn mọ pe awọn araalu yoo pariwo ti wọn ba bẹrẹ eto yii, o ṣi ṣee ṣe ko ṣakoba fun wọn lasiko idibo to n bọ.

Leave a Reply