Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Deji ilu Akurẹ, Ọba Aladeyoyinbo Aladelusi, ti ni ki gbogbo awọn to ba n gbero lati da ilu ru lasiko eto idibo to n bọ lopin ọsẹ yii maa mura lati fori gba epe awọn Alalẹ.
Deji ṣe ikilọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Michael Adeyẹye, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.
Ọba Aladeyoyinbo ni ọkan-o-jọkan ipade loun ti ṣe pẹlu awọn ti ọrọ kan lori idi ti wọn fi gbọdọ gba alaafia laaye ṣaaju ati lẹyin idibo naa.
O ni olori to ba mọ ojuṣe rẹ ko ni i laju silẹ ki iru rogbodiyan oṣelu to waye lọdun 1983 tun sẹlẹ mọ niluu Akurẹ ati agbegbe rẹ.
O ni ojuṣe awọn araalu ni ki olukuluku wọn jade lọọ dibo, ki wọn si pada sile wọn layọ ati alaafia.