Faith Adebọla
Awọn eeyan agbegbe Oro, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara, ti kede pe gbedeke ọjọ meje pere lawọn fun awọn Fulani darandaran to ba wa niluu naa ati lagbegbe rẹ, lati fi ibẹ silẹ lai sọsẹ. Wọn lawọn Fulani naa ko gbọdọ kọja ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu keji yii.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lorukọ ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Oro, eyi ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Alaaji Uthman Balogun, ati akọwe rẹ, Kayọde Oyeyipo buwọ lu, wọn ni awọn ti ṣakiyesi pe awọn Fulani ti wọn sa kuro lawọn agbegbe kan lati ipinlẹ Ọyọ lo fẹẹ tẹdo sagbegbe naa, ti wọn si ti pagọ sawọn ọna oko wọn.
Atẹjade naa tun fẹsun kan awọn baalẹ ati ọba alaye kan lagbegbe naa pe awọn fura si wọn pe wọn fẹẹ tọwọ bọwe adehun pẹlu awọn Fulani ati Bororo lati tẹdo sagbegbe ilu Oro.
Wọn lawọn o fara mọ adehun kan nibikibi to le mu kawọn Fulani darandaran wa lagbegbe naa, awọn si rọ awọn baalẹ ati ọba alaye tọrọ ba kan lati tete jawọ ninu ọrọ yii, tori lẹyin gbedeke ọjọ meje tawọn fun wọn yii, Fulani tabi Bororo eyikeyii tawọn ba kofiri rẹ lagbegbe naa gbọdọ fara mọ ohunkohun toju rẹ ba ri.
Wọn lawọn ti fi ẹda atẹjade naa ṣọwọ si kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ki ijọba ma sọ pe awọn mọ si i.