Awọn ara Ọyọ gbalejo: Adajọ ti ni ki wọn maa gbe Wakili atawọn ọmọ rẹ lọ si ọgba ẹwọn Abolongo

Ọgba ẹwọn to wa ni Abolongo, niluu Ọyọ, ni Adajọ agba ni ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ibadan, Onidaajọ Emmanuel Idowu, paṣẹ pe ki wọn maa gbe ọkunrin Fulani to ti n da awọn eeyan Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, laamu nni, Abdullahi Wakili atawọn ọmọ rẹ, lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ti igbẹjọ rẹ waye gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣe ṣalaye.

 

Ile-ẹjọ giga to wa ni Iyaganku, niluu Ibadan, ni igbẹjọ naa ti waye. Agbefọba to gbe awọn olujẹjọ naa wa sile-ẹjọ Adewale Amos ṣalaye pe ẹsun ijinigbe, ipaniyan, igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ati ole jija ni wọn fi kan wọn. Wakilu, ẹni aadọrin ọdun, atawọn ọmọ rẹ mẹta, Abu, ẹni ọdun marundinlaaadọta (45), Samailla, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), ati Aliyu Manu ẹni ogun ọdun (20) ni wọn jọ fara han niwaju adajọ.

Agbefọba, Adewale Amos, sọ niwaju ile-ẹjọ pe ni ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2015, ni Wakili, Abu, Samaila ati Manu gbimọ-pọ lati pa ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Akinwale Akande.

Bakan naa ni wọn tun ji obinrin kan ni nnkan bii aago mẹrin lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020, ni Idi-Ẹmi, nipinlẹ Ọyọ. Niṣe ni wọn dihamọra pẹlu ada atawọn ohun ija mi-in, ti wọn si tun gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira lọwọ obinrin naa.

Awọn iwa yii ni wọn lo lodi sofin, to si ni ijiya labẹ ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ọyọ n lo. Bẹẹ niwa ti wọn n hu naa ṣe lodi si ofin to de nini nnkan ija oloro lọwọ nipinlẹ Ọyọ ati ole jija pẹlu.

Adajọ ko tiẹ gbọ ẹbẹ lọọya wọn, Oritsuwa Uwawa, to waa ṣoju baba atọmọ naa to fi ni ki wọn maa ko wọn lọ si ọgba ẹwọn to wa ni Abolongo, niluu Ọyọ.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu karun-un, ọdun yii.

Tẹ o ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta ti ọkunrin naa ti n yọ awọn eeyan Ayetẹ, ni Ibarapa lẹnu, ko too di pe awọn ọmọ OPC lọọ koju rẹ, ti wọn si mu un, lẹyin eyi ni wọn fa a le ọlọpaa lọwọ, ibẹ naa lo si gba de ile-ẹjọ bayii.

Leave a Reply