Awọn ọmọ Yoruba ṣedaro Olupo tilu Ajaṣẹ-Ipo to waja

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn araalu ṣedaro Olupo tilu Ajaṣẹ-Ipo, Ọba Sikiru Atanda Ọladọtun Wọleọla (Ilufẹmiloye) to waja lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ lo papoda lẹyin aisan ranpẹ.

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti ba araalu Ajaṣẹ-Ipo, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, kẹdun iku ọba onipo kin-in-ni (First Class) naa.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, gbe sita laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Gomina Abdulrahman ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii akikanju ọkunrin, ẹni to fẹran araalu ilu ẹ, to si mu ilọsiwaju ba igbe-aye wọn ati ilu Ajaṣẹ-Ipo lapapọ.

Abdulrahman ba awọn oloye, mọlẹbi atawọn ọrẹ kabiyesi to waja naa kẹdun. O gbadura ki Ọlọrun tẹ ẹ safẹfẹ rere, ko si tu awọn to fi silẹ saye lọ ninu.

Ọdun 2009 ni Ọba Wọleọla gun ori oye gẹgẹ bii Olupo kẹẹẹdogun.

Ọba Wọleọla ni alaga gbogbo ọba ilẹ Igbomina nipinlẹ Kwara.

Leave a Reply