Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ni adugbo Sabo, niluu Ondo, ni awọn araalu ti ṣedajọ fun ọkan ninu awọn ole to jingiri ninu jiji ọkada gbe to n daamu awọn eeyan agbegbe naa.
Ọmọkunrin yii atawọn ẹlẹgbẹ rẹ ni wọn fẹẹ ji ọkada kan gbe lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja. Nibi to si ti n lọ ọkada mọ ẹni to ni in lọwọ niyẹn ti fariwo ta. Ariwo rẹ tawọn araadugbo gbọ ni wọn fi jade sita. Niṣe ni ọmọkunrin naa si sa lọ.
Ọmọkunrin yii ni wọn ni ki i ṣe igba akọkọ ti yoo waa jale ọkada lagbegbe naa. A gbọ pe yatọ si jiji ọkada gbe, o tun maa n ṣe afọwọra loriṣiiriṣii, bẹẹ lo si maa n halẹ mọ awọn eeyan adugbo naa.
Lẹyin to raaye sa lọ lọjọ Aiku lo tun pada wa si adugbo naa lọjọ Aje pẹlu awọn ikọ rẹ. Lasiko ti wọn tun fẹẹ ji ọkada gbe bii iṣe wọn ni ọwọ tẹ ọkan ninu wọn, ti oun atawọn yooku si raaye sa lọ.
Mimu ti wọn mu ọkan ninu wọn ọhun lọ si agọ ọlọpaa Fagun lo mu ki ọmọkunrin yii pada sibi iṣẹlẹ naa lati wo ohun to ṣẹlẹ si ẹni ti wọn mu naa, to si n beere ọkan ninu wọn ti wọn ti mu lọ sagọọ ọlọpaa ọhun.
Nigba ti ilẹ da diẹ lo pada wa lati waa mọ ohun to ṣẹlẹ si ọkan ninu wọn ti ọwọ tẹ naa. Nibẹ lawọn to da a mọ ti ri i, wọn ko si fakoko ṣofo rara, bẹẹ ni wọn ko si ṣopo pe ọlọpaa lori ọrọ rẹ, niṣe ni wọn ṣu bo o bii eṣu, ti wọn si lu u bii ejo aijẹ. Lẹyin ti wọn ti fiya ọwọ wọn jẹ ẹ ni wọn sọ taya sio i lọrun, ti wọn dana sun un.