Awọn araalu binu dana sun ọkọ, iyawo at’ọmọ wọn, wọn ni wọn n ṣagbodegba fawọn ajinigbe

Faith Adebọla

 Iṣẹ bonkẹlẹ ni iṣẹ ami ṣiṣe, iṣẹ naa ni wọn fẹsun kan baale ile kan, Abdullahi Mohammed ati iyawo rẹ, Binta Gobirawa, pe wọn n ṣe fawọn janduku agbebọn, ṣugbọn ba a ṣe n yọ so la n yọ gbọ, iṣẹ ọhun pa idile Gobirawa yii run nipinlẹ Kaduna lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, awọn araalu lo binu dana sun tọkọ-taya naa, wọn tun sun ọmọ kan ṣoṣo ti wọn bi, Hassan, pẹlu.

Ilu kan ti wọn n pe ni Zango Aya, nijọba ibilẹ Igabi, niṣẹlẹ naa ti waye.

Kọmiṣanna feto aabo ati ọrọ abẹle nipinlẹ Kaduna, Ọgbẹni Samuel Aruwan, fidi ẹ mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede pe awọn araalu naa ti n fura si igbesẹ ati isọrọ awọn tọkọ-tiyawo naa tipẹ, wọn si ṣakiyesi pe wọn n ni ajọṣe pẹlu awọn janduku agbebọn to n yọ awọn eeyan agbegbe naa lẹnu.

O ni iwadii tawọn agbofinro ṣe fihan pe awọn araalu naa fẹsun kan tọkọ-taya yii pe awọn ni wọn n ṣofofo fawọn agbebọn to n ji wọn gbe, awọn si ni wọn n juwe ọna abuja ti wọn le gba tawọn agbofinro ko fi ni i ri wọn mu ati asiko ti wọn maa wa fun wọn.

O ni bawọn tọkọ-taya naa ṣe n wọle lati ọna oko kan ti wọn fura pe ọdọ awọn agbebọn ni wọn ti n bọ lawọn araalu ko ara wọn jọ, wọn ya bo wọn mọle, wọn wọ wọn jade sẹgbẹẹ titi, wọn si ko taya mọto le wọn lori, ni wọn ba sọ wọn di suya.

Amọ ṣa o, Ọgbẹni Samuel ni Gomina ipinlẹ naa, Mallam Nasir El-Rufai, koro oju gidi si igbesẹ tawọn araalu naa gbe, pẹlu bi wọn ṣe ṣedajọ oju-ẹsẹ fawọn afurasi ọdaran ti wọn dana sun ọhun, ti wọn tun binu dana sun ọmọ wọn pẹlu.

O ni El-Rufai parọwa sawọn eeyan ipinlẹ naa pe loootọ ti wọn ba ro didun ifọ, wọn yoo họra de eegun, latari ọṣẹ tawọn janduku agbebọn ti ṣe fun wọn, ṣugbọn iru idajọ tinu-mi-ni-ma-a-ṣe bii eyi ko le yanju iṣoro, niṣe lo tubọ maa mu nnkan buru si i.

O ni ki wọn nigbagbọ ninu ofin ati idajọ ile-ẹjọ, ki wọn si mọ pe gbogbo ọna ni ijọba oun n ṣan lati fopin si iwa jatijati tawọn agbebọn naa n hu, ati awọn to n ṣonigbọwọ wọn pẹlu.

Leave a Reply