Awọn araalu binu nitori b’ọlọpaa ṣe ti awọn OPC to mu Wakilu niluu Ayetẹ mọle

Jide Alabi

Titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn eeyan n fi ibinu wọn han kaakiri ori ẹrọ ayelujara lori igbesẹ ti awọn ọlọpaa gbe pẹlu bi wọn ṣe ti mẹrin ninu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC to lọọ mu ọkunrin Fulani to n da awọn eeyan Ibarapa, paapaa ju lọ ilu Ayetẹ laamu, iyẹn Iskilu Wakili.

Awọn araalu ni iwa to ku diẹ kaato ni awọn agbofinro hu. Wọn ni dipo to fi yẹ ki wọn maa yin awọn ọmọ OPC to fori laku lọ lati lọọ mu awọn eeyan naa, niṣe ni wọn tun ti wọn mọle.

Ọkunrin yii ni wọn lo wa ninu awọn Fulani to n kọju ija si awọn eeyan Ibarapa, bẹẹ lo n fi maaluu jẹ oko wọn. Igba kan si wa to ta okun di awọn abule kan niluu naa, to ni awọn ara ilu naa ko gbọdọ debẹ, ẹni ti oun ba ri nibẹ, a jẹ pe ile aye ti su u ni, nitori oun maa pa a ni.

O pẹ ti awọn ara ilu Ayetẹ ti n pariwo ọkunrin to ti di ẹrujẹjẹ fun wọn ni ilu naa, ti wọn si n kegbajare fun ijọba lati gba wọn lọwọ rẹ. Ṣugbọn ijọba ko ri nnkan ṣe sọrọ naa nitori wọn ko ri awọn agbofinro ti wọn ṣeleri lati ko wa ki wọn le fi lọọ koju ọkunrin naa.

Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC lo dihamọra, ti wọn si wa ọkunrin Fulani yii lọ. Oju bọrọ kọ la fi n gbọmọ lọwọ ekurọ lọrọ naa da ko too di pe wọn ri ọkunrin naa mu ni ọjọ Aiku, Sannde, nitori ṣe ni wọn ni awọn ọmọ to wa lọdọ rẹ bẹrẹ si i yinbọn mọ awọn OPC yii.

Lẹyin ti wọn ri ọkunrin naa atawọn ọmọ kan ti wọn ba nibẹ pẹlu rẹ mu ni wọn fa a le ọlọpaa lọwọ.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe mẹrin ninu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ti wọn ṣiṣẹ naa lawọn ọlọpaa mu. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn dana sun ile Wakili, wọn si tun dana sun obinrin agbalagba kan sinu ile naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ ninu atẹjade kan to fi sita ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii pe loootọ ni aọn eeyan naa wa lagọọ ọlọpaa, awọn si mu wọn ki wọn le sọ ohun ti wọn ba mọ nipa bi wọn ṣe dana sun ile Wakilu, ti ẹni kan si jona mọle nibẹ.

Wọn ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i gba awọn araalu laaye lati ṣe ofin lọwọ ara wọn. Wọn ni awọn maa wadii iṣẹlẹ naa, awọn yoo si gbe igbeṣẹ to yẹ lai ṣegbe lẹyin ẹnikẹni.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọyọ ni kọmiṣanna ti paṣẹ pe ki aọn gbe Wakili lọ si ileewosan nitori aiya ara rẹ.

Leave a Reply