Awọn araalu binu sawọn aṣofin, nitori bi wọn ṣe ni ẹwọn ọdun mẹẹẹdogun lẹni to ba fun ajinigbe lowo yoo lọ

Faith Adebọla

Abadofin kan ti wọn ti gbe yẹwo lẹẹkeji nile-igbimọ aṣofin agba ilẹ wa, ninu eyi ti wọn ti ka a leewọ fẹnikẹni lati sanwo itusilẹ fawọn ajinigbe, tabi ki awọn to ba san iru owo bẹẹ lọọ fẹwọn ọdun mẹẹẹdogun jura, ti mu ki ọpọ araalu bẹnu atẹ lu sẹnetọ ilẹ wa, wọn lofin buruku lofin naa, o si lodi leti awọn eeyan.

Ọjọruu, Wẹsidee yii, lawọn aṣofin agba gbe ofin naa yẹwo lẹẹkeji, ti wọn si faṣẹ si i pe ofin daadaa ni, awọn yoo tubọ ṣiṣẹ lori ẹ ki wọn le gbe e yẹwo lẹẹkẹta, ki wọn si taari ẹ siwaju Aarẹ fun ibuwọlu rẹ lati sọ ọ di ofin gidi.

Sẹnetọ Francis Ezenwa Onyewuchi lati ẹkun idibo Ila-Oorun ipinlẹ Imo lo ṣagbatẹru abadofin ọhun.

Ninu abadofin naa, awọn aṣofin ọhun dabaa pe “ẹnikẹni to ba fowo ṣọwọ, sanwo tabi dunaa-dura pẹlu ajinigbe, agbebọn tabi afẹmiṣofo tori ko le gba ẹni ti wọn jigbe tabi ti wọn fi sigbekun wọn lọna aitọ ti dẹṣẹ to wuwo, ẹwọn onitọhun ko si gbọdọ din ni ọdun mẹẹẹdogun.”

Sẹnetọ naa ni idi tawọn fi gbe igbesẹ ofin yii ni akiyesi tawọn ṣe pe iwa ijinigbe ti fẹẹ di okoowo nla to n mowo wọle kiakia  lorileede yii, awọn si gbọdọ ṣe nnkan kan lati fopin si i.

Amọ awọn araalu ti bẹnu atẹ lu igbesẹ ati abadofin yii, wọn labadofin to ta ko araalu, ti ko si fi ifẹ ati aanu han ni.

Alukoro ẹgbẹ awọn lọọya ilẹ wa, NBA, Dokita Rapuluchukwu Nduka sọrọ lori abadofin naa, o ni “o ba ni lọkan jẹ pe awọn aṣofin wa o tiẹ sọrọ lori bi wọn ṣe fẹẹ ro awọn agbofinro lagbara lati dena iṣẹlẹ ijinigbe, wọn o sọrọ lori bi iṣẹlẹ ijinigbe o ṣe ni i waye, kaka bẹẹ, awọn araalu ni wọn fẹẹ fi jiya fun eto aabo to mẹhẹ. Ṣebi nigba ti awọn agbofinro wa gbogbo ko lagbara to lati koju awọn ajinigbe debi ti wọn maa gba awọn ti wọn ji gbe silẹ, tabi ki wọn ma tiẹ jẹ ki iṣẹlẹ ijinigbe waye rara, ṣebi iyẹn lo n mu kawọn eeyan ti ọrọ kan dẹni to n rababa wa owo kiri lati fi gba awọn eeyan wọn silẹ nigbekun awọn ajinigbe. Ofin to ta ko awọn araalu lawọn aṣofin wa n fakoko ṣofo le lori.”

Ọgbẹni Ṣegun Adebisi sọ pe “nigba tijọba atawọn agbofinro ko lagbara to lati gba awọn ti wọn jigbe silẹ, ṣe kawọn mọlẹbi kawọ gbera tori ofin yii, ki wọn si maa woran titi ti wọn fi maa fẹmi eeyan wọn ṣofo ni. Awọn aṣofin le ṣofin lori ẹni to fun awọn ajinigbe lowo, ṣugbọn wọn o le ṣofin lori ajinigbe to gbowo, ti wọn si fẹmi awọn araalu sinu ewu.”

Gbenga Ibigbami ni: “Emi o ro pe awọn aṣofin yii mọ ohun to kan fun wọn lati ṣe o. Ṣebi ijọba naa n fun wọn lowo, abi wọn o fun wọn ni. Ewo lo waa daa ninu ki wọn fun wọn lowo ati ki wọn fẹmi awọn to wa nigbekun wọn ṣofo. Tawọn aṣofin wa ba larojinlẹ, ko tiẹ yẹ kiru ofin yẹn kọja agbeyẹwo kan ki wọn too fawe ẹ ya sọnu.”

Leave a Reply

//byambipoman.com/4/4998019
%d bloggers like this: