Awọn araalu dana sun mọto ọmọ ‘Yahoo’ to paayan mẹta l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹta ni wọn pade iku ojiji, nigba tawọn mi-in tun fara pa ninu ijamba ọkọ to waye loju ọna marosẹ Ademulẹgun, niluu Ondo, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

ALAROYE gbọ latẹnu ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ ọhun pe ijamba ọhun waye laarin awakọ ayọkẹlẹ Toyota Camry kan pẹlu onikẹkẹ Maruwa to n ṣiṣẹ oojọ rẹ lọwọ.

O ni ọmọ ‘Yahoo’ kan lawọn fura si pe o wa ọkọ naa, ati pe ere asaju to n sa lo mu ko padanu ijanu ọkọ rẹ to fi lọọ kọ lu kẹkẹ Maruwa to n lọ jẹẹjẹ ẹ loju ọna tirẹ.

Loju-ẹsẹ ni onikẹkẹ Maruwa ọhun ati ọkan ninu awọn ero marun-un to gbe ti ku, ti awọn mẹrin yooku si  fara pa yannayanna.

Loootọ lawọn alaaanu kan sare gbe awọn to fara pa lọ sile-iwosan fun itọju, ṣugbọn wọn ko ti i de ọhun ti ọkan ninu wọn tun fi ku, leyii to mu kawọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa rin lọjọ yii jẹ mẹta.

Kiakia lọmọ ‘Yahoo’ to kọ lu wọn ti sa lọ, ti awọn ọdọ to wa nibi iṣẹlẹ ọhun naa ko si roo roo lẹẹmeji ti wọn fi dana sun ọkọ rẹ.

 

Leave a Reply