Awọn araalu fẹhonu han l’Ọgbẹsẹ, wọn lawọn ajinigbe ko jẹ ki awọn sinmi

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọgọọrọ awọn eeyan ni wọn jade niluu Ọgbẹsẹ, n’ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta ta a wa yii lati fẹhonu han lori ọrọ ijinigbe to n waye lemọlemọ lagbegbe naa

Awọn olufẹhonu han ọhun ni wọn di oju ọna marosẹ Akurẹ-Ọwọ-Benin, to gba ilu Ọgbẹsẹ kọja, fun bii wakati mẹrin gbako, ti ko si si ọkọ tabi awọn arinrin-ajo to raaye kọja laarin asiko ti ifẹhonu naa fi waye.

Wọn ni inu awọn araalu ọhun ko dun rara lori bawọn agbebọn ṣe n fi igba gbogbo ji awọn eeyan wọn gbe, ti ko si sẹni to laya lati lọ sibi iṣẹ oojọ wọn mọ nitori ibẹru.

Wọn ni awọn n ṣe iwọde alaafia naa ki ijọba le gbe igbesẹ to yẹ lori iṣẹlẹ ọhun, nitori ọkan awọn eeyan ko bakẹ mọ latari ọsẹ buruku ti awọn ọdaju naa n ṣe.

Awọn ṣọja la gbọ pe wọn pada tu awọn olufẹhonu ọhun ka lẹyin-o-rẹyìn tawọn eeyan fi raaye kọja.

 

 

Leave a Reply