Awọn araalu le jade lati aago mẹjọ aarọ si aago mẹfa alẹ lati ọjọ Satide – Sanwo-Olu

Faith Adebọla, Eko

Lati Satide, ọjọ Abamẹta, awọn eeyan ipinlẹ le maa jade lati aago mẹjọ aarọ si aago mẹfa alẹ. Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lo kede ọrọ naa lasiko to n ba gbogbo araalu sọrọ lori bo ṣe dẹ ikede konilegbele to ṣe nipinlẹ Eko. Bẹẹ lo kilọ fun awọn ọdọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ ṣe ifẹhonu han kankan mọ, o ni o ti to gẹẹ.

‘Fun itẹnumọ, gbogbo eeyan ipinlẹ Eko le jade lati aago mẹjọ aarọ si mẹfa alẹ sibi ti onikaluku ba fẹẹ lọ,’ Sanwo-Olu lo sọ bẹẹ.

Leave a Reply