Awọn araalu pariwo: Ta lo waa gbe ọmọ oojọ ju sabẹ biriiji ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Epe rabandẹ rabandẹ lawọn eeyan n gbe ọdaju abiyamọ kan tẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ, tabi ibi to ti wa ṣẹ pe nibi ti ọpọ ti n sunkun airi bi, ti wọn n gbaawẹ airi pọn, ni ọdaju abiamọ kan ti lọọ gbe ọmọ tuntun, ọmọ oojọ kan, si abẹ biriji agbegbe Òkè-Fòmá, Ìta-Ǹmá, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.

Ọpọ awọn ti ko rọmọ bi to n woju Ọlọrun ko ni i fojuure wo ọdaju eeyan to ru oyun fun oṣu mẹsan-an, to si bi ẹjẹ ọrun naa, ti ko waa ri ohun kan mi-in ṣe ju ko gbe ọmọ naa silẹ, ko si ba tirẹ lọ lọ.

Niṣe lawọn eeyan pe pitimu le ẹjẹ ọrun naa lori, ti wọn si n rọjo epe lọlọkan-o-jọkan si obinrin to dan iru eyi wo, wọn ni ko le ri iyọnu Ọlọrun.

Arakunrin kan, Abdulazeez, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe sadeede lawọn olugbe agbegbe naa ri ọmọ tuntun ti wọn gbe si abẹ biriiji ọhun, ti ko si sẹni to mọ ẹni to gbe ọmọ naa sibẹ. O tẹsiwaju pe ohun iyanu ni iṣẹlẹ naa jẹ, tori pe ọpọ lo n pariwo, ti wọn si n sunkun si Ọlọrun lọrun lojoojumọ pe Ko fun awọn lọmọ, ti ẹnikan si bi tirẹ, to gbe e ju silẹ, to sa lọ.

Awọn ẹlẹyinju aanu to wa lagbegbe naa lo gbe tuntun ọhun, wọn wẹ fun un, wọn si wọ aṣọ fun un. Lẹyin gbogbo itọju ti wọn ṣe fun ọmọ naa ni wọn fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Leave a Reply