Awọn awakọ tanka lawọn yoo daṣẹ silẹ tijọba ko ba ṣatunṣe awọn ọna marosẹ to bajẹ

Faith Adebọla

Afaimọ ni ki ọwọngogo epo bẹntiroolu ati wahala riri epo ra ma tun bẹ silẹ lorileede wa lasiko yii pẹlu bawọn awakọ tanka epo ṣe fariga pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi lonii, ọjọ Aje, Mọnde, wọn ni gbogbo ọna tawọn n tọ lo ti bajẹ kọja afẹnusọ, ijọba ko si ṣatunṣe si wọn.

Ẹgbẹ awọn onitanka epo naa, Petroleum Tanker Drivers (PTD), to jẹ ẹka ẹgbẹ NUPENG sọrọ yii di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, wọn ni lati ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹsan-an, to kọja, lawọn ti fi gbedeke lede pe iyanṣẹlodi yoo bẹrẹ lọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, tijọba ko ba da awọn lohun idaniyan awọn.

Lara ohun to jẹ ẹdun ọkan awọn onimọto naa ni awọn titi marosẹ, tijọba apapọ ati tipinlẹ, to ti di pakute iku kaakiri ọpọlọpọ agbegbe lorileede yii, wọn ni adanu nla lawọn n koju rẹ pẹlu bawọn tanka wọn ṣe n doju de, ti asidẹnti si n ṣẹlẹ loorekoore.

Yatọ si iṣoro ọna, awọn awakọ naa tun sọrọ nipa bijọba ṣe kuna lati so ẹrọ ti yoo maa daabo bo epo tabi afẹfẹ gaasi ti ajagbe pọn sẹyin lati ma ṣe tete ṣẹ danu tabi ṣofo. Wọn niṣe lawọn onitanka ati awọn oṣiṣẹ to n pọn epo maa n di adipele ẹru fun awọn, eyi si n mu akoba gidigidi wa.

“Ta a ba ni ka maa to awọn ọna marosẹ to ti bajẹ kọja aala lorileede yii, wọn pọ gidi ni, ipọnju ati wahala aṣekurodogbo si lawọn awakọ tanka n ṣe lati wakọ lawọn ọna koto iku wọnyi ka le ri i pe a gbe epo ati afẹfẹ idana de awọn ileeṣẹ to maa ta a faraalu, tọsan-toru.”

Ọkan lara awọn adari ẹgbẹ PTD to ba iweeroyin Vanguard sọrọ sọ pe awọn maa ṣe ipade pajawiri kan lọjọ Ẹti, lẹyin ipade lawọn yoo gbe ipinnu ati igbesẹ to kan jade.

Leave a Reply