Awọn bọis n ja si ọmọge kan, ni wọn ba ba mọto mẹẹẹdọgbọn jẹ n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ọdọ kan lagbegbe Ọlọ́jẹ̀ ati Ìta-mẹ́rin, niluu Ilọrin, da rogbodiyan silẹ nitori ọmọbinrin kan ti wọn n ja si, Aisha, to jẹ akẹkọọ ọlọdun keji akọkọ nileewe girama (JSS 2), ni wọn ba tori ẹ ba ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ jẹ, wọn fi ọpọ dukia ṣofo, wọn ji awọn ẹru kan ko, n ni ọlọpaa ba ko bii ọgbọn lara wọn da satimọle.

ALAROYE, gbọ pe alẹ ọjọ Ẹti, Furaide, opin ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii ni awọn ọdọ ọhun to wa ni agbegbe Ọlọ́jẹ́, niluu Ilọrin, ati awọn ọdọ kan ni agbegbe Ìta-Mẹ́rin, gbe pẹrẹgi ija kana, ti wọn da wahala nla kalẹ latari pe wọn n ja si Aiṣha ti wọn lo jẹ ọrẹbinrin ọkan ninu wọn. ‘Iyawo mi ni, fi i lẹ fun mi, emi ni mọ kọkọ dẹnu ifẹ kọ ọ, mi o gba’ ni wọn ni o ṣokunfa rogbodiyan naa, niṣe lawọn gende yii ko ada, aake, igo ati bẹẹ bẹẹ lọ, wọn bẹrẹ si i da omi alaafia ilu ru, mọto to le ni mẹẹẹdọgbọn ni wọn fọ gilaasi rẹ lasiko rogbodiyan naa.

Arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Titilayọ Mariam, ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, sọ fun ALAROYE pe ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wahala naa bẹrẹ, nigba ti awọn ọdọ agbegbe Ọlọ́jẹ́, ya bo agbegbe Ìta-Mẹ́rin, pẹlu oniruuru ohun ija oloro, ti jinnijinni si bo gbogbo adugbo, ko si ẹni kan to le foju le oorun. Amọ ni nnkan bii aago meji oru ti awọn fijilante ati ọlọpaa gunlẹ sibi iṣẹlẹ naa ni gbogbo nnkan too pada bọ sipo.

O tẹsiwaju ọmọde ni gbogbo awọn to n ja nitori ọmọbinrin yii, o ni eyi to dagba ju ninu wọn ni ẹni ọdun mejidinlogun, o fi kun un pe nigba ti ilẹ mọ lọjọ Abamẹta, Satide yii, ni ọlọpaa bẹrẹ si i ko gbogbo wọn, omiiran ti sa lọ ti ọlọpaa si ti ko iya ati baba wọn.

Arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Yunusa Oloduku, to ba ALAROYE sọrọ lagbegbe Ọlọ́jẹ́, sọ pe awọn ko ri oorun sun lati alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, mọju ọjọ Abamẹta, Satide yii. O ni ohun to jọ oun loju ju ni pe ọmọde ni gbogbo awọn to n fa wahala naa, bi wọn ṣe n ba dukia jẹ ni wọn n ja ṣọọbu, ti wọn si n ko dukia oni dukia lọ, ṣugbọn awọn aṣoju adugbo Ọlọ́jẹ́ àti Ìta-Mẹrin ni wọn ṣe akitiyan, ti wọn fi n ri awọn ọmọ janduku naa ko, ti wọn si ko eeyan to n lọ bii ọgbọn. O tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa ni ki obi kọọkan lọọ wa ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (50,000), wa gẹgẹ bii owo itanran, bẹẹ ni wọn ni ki gbogbo awọn ti dukia wọn bajẹ lọọ yọwo iye ti dukia wọn jẹ, wọn ni awọn obi wọn ni yoo san gbogbo gbese naa tori pe ẹni to bimọ ọran naa ni yoo pọn ọn.

Nigba ti ALAROYE, de agọ ọlọpaa D’Division, nibi ti wọn ko awọn tọwọ tẹ si, ṣe ni ẹsẹ ko gbero ni agọ naa, ọpọ mọlẹbi awọn ti wọn mu n sapa lati gba eeyan wọn silẹ. DPO agọ ọlọpaa naa, Dare Afọnja, sọ pe oun ko le sọ nnkan kan lori iṣẹlẹ naa tori alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara nikan lo ni aṣẹ lati ba awọn oniroyin sọrọ.

Leave a Reply