Awọn darandaran mẹtadinlogoji ati ẹgbẹrun marun-un maaluu la ti le kuro nigbo ọba- Adelẹyẹ

 Iyiade Oluṣẹyẹ, Akurẹ

Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ti fidi rẹ mulẹ pe awọn Fulani bii mẹtadinlogoji ati maaluu to le lẹgbẹrun marun-un lawọn ti le kuro lawọn igbo ọba to yi ipinlẹ Ondo ka.

Ni ibamu pẹlu alaye ti Oloye Adelẹyẹ ṣe fawọn oniroyin kan lọjọ Ẹti, Furaidee, o ni igbesẹ yii waye lẹyin ti gbedeke ọjọ meje ti Gomina Rotimi Akeredolu fun gbogbo awọn Fulani to n daran ninu igbo ọba lọna aitọ pari lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja.

Adelẹyẹ ni ilana ti gomina fi lelẹ fawọn Fulani wọnyi ni lati waa maa forukọ silẹ lọdọ ijọba, ki wọn le ni akọsilẹ gbogbo awọn to ba wa ninu igbo ọba to jẹ tipinlẹ Ondo.

Ọsẹ to kọja yii lo ni alaga ẹgbẹ Miyẹtti Allah, ẹka tipinlẹ Ondo, ko awọn ọmọ abẹ rẹ kan wa si ọfiisi ẹsọ Amọtẹkun to wa ni Alagbaka, nibi ti wọn ti jọ ṣepade alaafia lori aṣẹ tuntun naa.

O ni pupọ awọn darandaran ti ko lanfaani ati tẹle awọn alakalẹ ijọba ni wọn gba lati kuro ninu igbo ọba funra wọn, ti wọn si pinnu ati ko ẹran wọn lọ si awọn ipinlẹ bii Ọsun, Edo ati Kogi.

O ni awọn ẹsọ Amọtẹkun ri i daju pe wọn sin awọn Fulani ọhun de aala ipinlẹ Ondo ki wọn too pada lẹyin wọn.

Leave a Reply