Awọn dokita nipinlẹ Ondo bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ

Aderounmu Kazeem

Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn dokita oniṣegun oyinbo bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ nipinlẹ Ondo, lẹyin ti wọn ti kọkọ fi iyanṣelodi ọlọsẹ kan fa ijọba leti.

ALAROYE gbọ pe ohun to fa iyanṣẹlodi ọhun ni bi ijọba ipinlẹ Ondo ṣe kọ lati sanwo oṣu mẹrin ataabọ to jẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera naa. Bakan naa ni wọn ni ijọba ko san owo iṣẹ koro ti awọn ṣe ati awọn ajẹmọnu mi-in.

Adele Aarẹ fun ẹgbẹ awọn dokita l’Ondo, Dokita Sanni Oriyọmi, ṣalaye fawọn oniroyin pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ko le maa pa ebi mọnu fi ṣiṣẹ mọ, ati pe ki i ṣe owo-oṣu mẹrin aabọ nikan ni ijọba jẹ awọn, owo ajẹmọnu to yẹ ki awọn gba lori COVID 19, iyẹn itọju alaisan ti arun koronafairọọsi mu atawọn owo ajẹmọnu mi-in naa wa ninu ẹtọ tawọn fẹẹ gba lọwọ ijọba Ondo.

Sanni sọ pe bi ijọba Ondo ko ṣe sọ ohunkohun lasiko igba ti awọn fi yanṣẹ lodi lọsẹ to kọja gan-an lo fa eyi ti awọn ti gun le bayii, bẹẹ ọlọjọ gbọọrọ lo maa jẹ.

Lọsẹ to kọja lawọn dokita ọhun kọkọ lọ fun iyanṣẹlodi ọlọsẹ kan lati fi fa ijọba leti. Bi ijọba ko ṣe sọrọ lori ẹ ni wọn lo mu wọn gbe igbesẹ lati lọ fun ọlọjọ pipẹ bayii.

 

Leave a Reply