Awọn ẹbi ti sọrọ: Ironu iku Oriṣabunmi lo pa aburo rẹ lojiji, ko sẹni to ko Korona ninu wọn

Kazeem Aderounmu

Alhaji Fatai Adeniyi, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Dan Kazeem, ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri pe arun Koronafairọọsi lo pa Oriṣabunmi atawọn mọlẹbi ẹ meji to ku laarin ọsẹ kan sira wọn.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni Dan Kazeem, ẹni ti i ṣe ọkọ aburo Oloogbe Fọlakẹ Arẹmu tawọn eeyan tun mọ si Oriṣabunmi, sọrọ yii fun akọroyin wa.

O sọ pe inu awọn mọlebi ko dun rara si iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri nipa awọn mọlẹbi mẹtẹẹta ti wọn doloogbe leralera yii pe arun Koronafairọọsi lo pa wọn.

Bakan naa lo fidi ẹ mulẹ pe aburo Oriṣabunmi, iyẹn Janet Ademọla, to jade laye lọjọ Abamẹta, Satide, ti ni aisan ẹjẹ riru tẹlẹ, ati pe iku ojiji to pa gbajumọ oṣere nni, Oriṣabunmi, ti ṣe ẹgbọn ẹ, ati ẹgbọn wọn agba to tun ku lo ko ironu ba a ti oun naa fi jade laye.

Ọkunrin oṣere tiata to tun jẹ gbajumọ sọrọsọrọ to fi ilu Ilọrin ṣebugbe sọ pe ko si ẹnikẹni ninu awọn oloogbe ọhun ti arun Koronafairọọsi kọ lu, bo tilẹ jẹ pe niṣe ni iku wọn tẹle ra laarin ọsẹ kan pere.

Ni bayii, iyawo Dan Kazeem, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Alhaja Mama Ọlamilekan, nikan lo ku ninu ọmọ iya wọn, nitori awọn mẹrin ni awọn obi wọn bi, mẹta ninu wọn lo si ku lojiji lera wọn yii. Bẹẹ lawọn obi wọn mejeeji ti ku pẹlu.

Leave a Reply