Awọn eeyan ṣedaro Arotile, obinrin akọkọ to jagun pẹlu baaluu agberapa

Oluyinka Soyemi

Lati ana, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti iroyin iku Tolulọpẹ Arotile ti gba igboro kan lawọn eeyan ti n daro ọmọbinrin to dagbere faye lẹni ọdun mẹrinlelogun pere ọhun.

Arotile ni obinrin akọkọ to fi baaluu agberapa jagun lati ofurufu ninu itan awọn ọmọ-ogun ofurufu, ko si ti i pe ọdun kan to bẹrẹ iṣẹ naa ti iku pa oju rẹ de.

Arotile ninu baaluu agberapa

Lanaa lo nijamba ọkọ ni ibudo awọn ọmọ-ogun ofurufu to wa ni Kaduna, ori lo si ti fara pa, eyi to fa iku ojiji fun un.

Latigba ti iroyin iku ẹ ti jade lawọn ọmọ ilẹ yii ti n ṣedaro rẹ nitori aṣeyọri to ṣe, eyi to wu ọpọ eeyan lori, ati nitori pe ọjọ ori ẹ kere jọjọ.

Ninu atẹjade kan to fi sita, Ọgagun Sadique Abubakar to jẹ olori ọmọ-ogun ofurufu nilẹ yii sọ pe ilẹ Naijiria ti padanu ọkan ninu awọn olokiki rẹ.

Abubakar, ẹni to fun Arotile laṣẹ lati di jagunjagun pẹlu baaluu sọ ọ di mimọ pe oloogbe ọhun jẹ olufọkansin, o si ṣe bẹbẹ lati da alaafia pada si agbegbe Niger, nibi tawọn afẹmiṣofo ti n ṣọṣẹ.

Leave a Reply