Awọn eeyan Amuwo-Ọdọfin fẹẹ yọ Ọnarebu Mojisọla nipo, wọn lawọn o fẹ ẹ mọ

Faith Adebọla, Eko

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni ki wọn ma juwe ọna ile fun Ọnarebu Mọjisọla Alli-Macauley nileegbimọ aṣofin Eko, afaimọ si ni ko ma padanu ipo rẹ gẹgẹ bii aṣoju Amuwo-Ọdọfin nipinlẹ Eko, latari bi awọn eeyan agbegbe naa ṣe pinnu pe yiyọ lawọn fẹẹ yọ ọ kuro nipo aṣofin awọn.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, lorukọ awọn alẹnulọrọ, awọn agbaagba ati awọn eeyan agbegbe Amuwo Ọdọfin ni wọn ti sọ ipinnu wọn pe awọn fẹ ki aṣofin naa pada wale, awọn o fẹ ko maa ṣoju awọn nile-igbimọ aṣofin Eko mọ, ẹlomi-in lawọn fẹẹ fi rọpo ẹ, ẹsun mẹfa ọtọọtọ ni wọn ka si i lọrun.

Lara wọn ni pe lati bii ọdun meji tobinrin naa ti n ṣoju wọn, ko ni ọfiisi kan tawọn ti le kan si i lagbegbe naa, leyii to lodi sofin ilẹ wa, bẹẹ ni wọn ni aṣofin naa ko ti i kọ abadofin eyikeyii fun odidi ọdun meji, wọn ni niṣẹ lo kan lọọ jokoo faaji nibẹ. Ati pe o lu awọn eeyan rẹ ni jibiti, wọn ni irẹsi atawọn ounjẹ to gba lọdọ ijọba pe oun fẹẹ pin fun wọn ni lo sọ di ẹbun ọjọọbi ẹ, to kọ orukọ ati fọto ẹ si lara, to si n pin in fawọn ọrẹ ẹ nigba to ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ loṣu to kọja yii, bẹẹ ounjẹ iranwọ lasiko korona lawọn nnkan naa.

Wọn tun ni obinrin naa ki i gbele, ko lọfiisi tawọn le waa si, awọn ki i ri i ba sọrọ rara latigba to ti wọle ibo, niṣe lo ta awọn nu, ori tẹlifiṣan lawọn ti maa n ri i lẹẹkọọkan, o si ti sọ ile rẹ di igbalẹ eegun ti ko ṣe e wọ fẹnikẹni.

ALAROYE gbọ pe wọn ti taari lẹta ibeere iyọnipo aṣofin ọhun si akọwe ileegbimọ aṣofin pe ki wọn ba awọn ṣiṣẹ lori ẹ, wọn si kọ ẹda kan si ọfiisi ajọ eleto idibo ipinlẹ Eko, LASIEC.

Leave a Reply