Awọn eeyan ba Akeredolu daro lori iku iya rẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan-o-jọkan awọn ọrọ ibanikẹdun lawọn eeyan ti n fi  ranṣẹ si Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, lori iku iya rẹ, Abilekọ Grace Akeredolu, ẹni to ku laaarọ kutukutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lẹni aadọrun ọdun.

Gomina Akeredolu lo kọkọ kede iku iya ẹni aadọrin-ọdun ọhun fawọn eeyan ninu atẹjade kan to fi sita lori ikanni Fesibuuku rẹ ni kete ti iṣẹlẹ yii waye.

Aketi ninu ọrọ rẹ ni bo tilẹ jẹ pe ọrọ iku iya awọn ba awọn ninu jẹ pupọ, sibẹ, itunu ati ayọ lo jẹ foun atawọn ọmọ iya oun yooku pe ijọba ọrun taara lawọn angẹli gbe e lọ.

Arakunrin ni oun gbadura ki Ọlọrun ba awọn tẹ iya awọn si afẹfẹ rere, o si fi da awọn araalu loju pe awọn ko ni i jẹ ki eti wọn di si bi eto isinku iya ti wọn n pe ni Ẹfanjẹliisi naa yoo ṣe lọ laipẹ.

Ni kete ti iroyin yii ti jade lawọn eeyan ti bẹrẹ si i ranṣẹ ibanikẹdun si gomina ọhun.

Lara awọn to ba a daro ni ẹgbẹ oniroyin, ẹka ti ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Adegoroye Ademọla, minisita fun eto irinna kekere atawọn mi-in.

Leave a Reply