Awọn eeyan bara jẹ gidigidi nibi isinku agunbanirọ to ku ninu ijamba ọkọ BRT ati reluwee l’Ekoo

Faith Adebọla

Niṣe lomije n pe omije ranṣẹ nibi isinku Ọrẹoluwa Aina, ọkan ninu awọn to padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ reluwee ati ọkọ gbọgbọrọ BRT tijọba fi n ko awọn oṣiṣẹ, eyi to waye laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta yii. Ọmọbinrin naa ti dẹni akọlẹbo.

Itẹkuu Atan, eyi to wa lọna University Road, lagbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, ni wọn sinku ọdọbinrin rọgbọdọ, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, to rẹwa daadaa, to n ṣiṣẹ aṣesinlu rẹ si, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu yii.

Ọgọọrọ awọn mọlẹbi oloogbe yii ni wọn ko le mu omije wọn mọra, wọn bara jẹ gidi nigba ti awọn agunbanirọ ti wọn n yan bii ologun gbe posi ti wọn ta asia orileede Naijiria sara rẹ, eyi ti wọn fi gbe oku Ọrẹoluwa, lati ṣẹyẹ ikẹyin fun un.

Kọmiṣanna feto ẹkọ, Abilekọ Fọlaṣade Adefisayọ, to ṣaaju ikọ awọn to ṣoju fun ijọba ipinlẹ Eko, wa nibi iṣẹlẹ naa.

Gbogbo arọwa ati iṣipẹ ti wọn ṣe fun awọn mọlẹbi ati awọn agunbanirọ ẹlẹgbẹ oloogbe yii ko da ẹkun asunwa wọn duro, niṣe lomije n da loju wọn bii ojo arọọda.

Ẹka to n bojuto eto ẹkọ nipinlẹ Eko, Ministry of Education, ni Curriculum Services Department, ni sẹkiteria ijọba Eko, eyi to wa l’Alausa, n’Ikẹja, ni agunbanirọ yii ti n ṣiṣẹ aṣesinlu rẹ.

Ibiiṣẹ ọhun lo mura gẹgẹ bii iṣe rẹ lọjọ Tọsidee, ọjọ buruku eṣu gbomi mu ọhun, to fi wọ ọkọ BRT ni agbegbe Isọlọ, to n gbe, nigba ti ọjọ naa si jẹ ọjọ tawọn agunbanirọ maa n ṣe ipade ọsọọsẹ wọn, aṣọ kaki agunbanirọ lo wọ, laimọ pe igba ikẹyin toun maa wọṣọ ọhun laaye niyẹn. Bo tilẹ jẹ pe imura agunbanirọ ọhun ni wọn wọ fun un ninu posi ti wọn fi sin in, ṣugbọn Ọrẹoluwa ko le gbapa gbẹsẹ mọ, ko si le yan bii ologun mọ, gbogbo ireti ati erongba rẹ fọjọ iwaju ti wọmi.

Ba a ṣe gbọ, ọgangan ibi ti ọdọmọbinrin yii jokoo si ninu ọkọ BRT naa, lagbedemeji ọkọ ọhun, ni reluwee fori sọ, ko too run BRT ọhun jege, to si wọ ọ niwọọkuwọọ siwaju, nibi to fi i ti si.

Ọrẹoluwa Aina wa lara awọn meji ti wọn gbe jade lokuu ninu ọkọ ọhun lọjọ naa.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti ṣabẹwo sawọn mọlẹbi ti wọn padanu eeyan wọn ninu iṣẹlẹ agbọbomiloju yii.

Gẹgẹ b’Alaroye ṣe royin tẹlẹ, adugbo PWD si Ṣogunlẹ, niṣẹlẹ yii ti waye lọjọ Tọsidee to kọja, nigba ti ọkọ BRT yii ya wọle lati maa lọ si Ikẹja, amọ niṣe lo jana mọ reluwee lẹnu lojiji ni ikorita ọhun, ko duro bi awọn ọkọ yooku ṣe duro ki reluwee kọja, bẹẹ ni ko telẹ ami ati ikilọ awọn oṣiṣẹ reluwee ti wọn gbe asia pupa soke, eyi to jẹ ami pe o lewu gidi fun ohunkohun lati  kọja oju-irin lasiko naa, eyi to mu ki reluwee naa ka ọkọ ọhun mọ, ni gọngọ ba sọ.

A gbọ pe o ti aadọta lara awọn eeyan bii aadọrun-un ti wọn n gba itọju lọwọ, tara wọn ti mokun pada, ti wọn si ti ni ki wọn maa lọ sile wọn lalaafia. Eeyan mẹjọ la gbọ pe wọn ko rọgbọn da sọrọ tiwọn, wọn ba iṣẹlẹ naa rin, Ọrẹoluwa ti wọn sinku rẹ yii wa lara wọn.

Leave a Reply