Awọn eeyan bara jẹ gidigidi nibi isinku Oriṣabunmi ni Kwara

Aderounmu Kazeem

 

Bii omi lawọn eeyan ṣe ya wọ ilu kan ti wọn n pe ni Ọlla, nijọba ibilẹ Isin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Aje, Mọde, ọsẹ yii nigba ti wọn gbe oku gbajumọ oṣere tiata nni, Fọlakẹ Arẹmu, waa sin siluu ọhun.

Pẹlu omije loju ni wọn fi gbe obinrin oṣere yii wọ kaa ilẹ lọ lẹyin isin ranpẹ ti wọn ṣe fun un.

Ọkan lara gbajumọ oṣere tiata, to tun jẹ apẹsa, Ọgbẹni Abdullahi Atọlagbe, ẹni tawọn eeyan tun mọ si AMJA to wa nibi isinku naa ṣalaye fun ALAROYE pe “Niṣe lawọn eeyan bara jẹ gidi gan-an, ti ibanujẹ si han loju kaluku pẹlu. Oṣere nla ti awọn eeyan ko ni i gbagbe bọrọ ni Oriṣabunmi, bẹẹ ni wọn ṣẹyẹ nla fun un, ki wọn too gbe e sinu saare.”

Ọkunrin yii fi kun un pe pupọ ninu awọn oṣere tiata Yoruba ti wọn wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni wọn wa nibẹ lati ṣeyẹ ikẹyin fun un, bẹẹ lawọn ti Kwara, eyi ti Alhaji Fatai Adeniyi Dan Kazeem ṣaaju wọn wa naa ko gbẹyin rara.

Lọjọ Aje, Mọnde, ni wọn gbe oku Oriṣabunmi kuro niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyo. Iwo Road, niluu Ibadan, ni awọn oṣere ẹgbẹ ẹ atawọn mọlẹbi ti pade, ti wọn si fori le ipinlẹ Kwara pẹlu oku akọni obinrin yii.

Ẹni ọgọta ọdun ni wọn pe oloogbe yii lasiko to jade laye. Bẹẹ la gbọ pe wọn ti sin awọn mọlẹbi ẹ mejeeji; ẹgbọn ẹ, Steve Oniṣọla, ati aburo ẹ, Janet Ademọla, ti wọn ku ninu ọsẹ kan naa ti Oriṣabunmi jade laye.

Pupọ ninu awọn oṣere ti wọn wa niluu Ibadan bii Tọwọdun, Ogunjimi atawọn mi-in ni wọn wa nibi isinku ẹ, ohun ti kaluku si n sọ ni pe obinrin naa gbiyanju daadaa nidii iṣẹ sinima Yoruba, ati pe ipa manigbagbe to ko lawọn eeyan yoo maa ranti laelae.

Leave a Reply