Stephen Ajagbe, Ilorin
Eeyan ti ko niye lo fara pa laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba ti afẹfẹ gaasi ṣadeede bu gbamu nileepo Bovas, to wa ni Ọffa Garage, niluu Ilọrin.
ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago mọkanla aarọ niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Ẹnikan to ṣoju ẹ ṣalaye pe ṣadeede lawọn gbọ iro bii ado oloro to bu, n lonikaluku ba fẹsẹ fẹ ẹ.
O ni ṣe ni eefin bo gbogbo inu ile-epo naa, gbogbo ọkọ atawọn ọlọkada to fẹẹ ra epo bẹrẹ si i rọ lu ara wọn lasiko ti onikaluku n wa ọna lati sa kuro nibẹ.
Awọn to n ta ọja niwaju, atawọn to n kiri ọja kaakiri inu ile-epo naa fere ge e, awọn to le du ọja wọn ṣe bẹẹ, ṣugbọn awọn mi-in pa ọja ti lati kọkọ du ẹmi ara wọn na.
ALAROYE gbọ pe tanki gaasi kan ti wọn fi n ta afẹfẹ idana lo bu. Awọn oṣiṣẹ ile-epo naa lo si sare pana kinni ọhun ti ko fi di ohun tagbara ko ni i ka.