Florence Babaṣọla, Ọṣogbo
Latigba ti iroyin ti gbe iku gbajugbaja olorin ati afọnfere nni, Orlando Julius Ekemode, ẹni ti ọpọ mọ si OJ, ni awọn ọmọ bibi ilu abinibi rẹ ni Ijẹbu-Jeṣa, nipinlẹ Ọṣun, ti n ṣedaro rẹ.
Ọba ilu naa, Ọba Moses Agunsoye, ṣalaye pe adanu nla ni iku ọkunrin to jẹ Gbeluniyi ti ilu Ijẹbu-Jeṣa ọhun, o ni idaji ọjọ Furaidee lo jade laye, bo si ṣe pajude ni nnkan bii aago mẹta idaji ni wọn pe oun.
Ọba Agunsoye sọ siwaju pe lati nnkan bii ọdun meji ataabọ sẹyin ni Orlando Julius ti pada wa sile, to si n gbe lagbegbe Ireti Ayọ, niluu Ileṣa, pẹlu iyawo rẹ, Latoya Ekemode, eni to jẹ ọmọ orileede Amẹrika.
Kabiesi ni ọkan pataki lara awọn to gbe orukọ ilu naa kaakiri ni oloogbe jẹ, idi niyẹn ti oun si ṣe fi oye Gbeluniyi da a lọla, ti oun si tun fi iyawo rẹ jẹ Yeye Aṣa.
O ni o ti ṣe diẹ ti aisan ti da baba naa gunlẹ ko too di pe o ku si ọwọ iyawo rẹ. O fi kun un pe gbogbo ọmọ ilu naa, awọn eeyan ijọba ibilẹ Oriade ati ipinlẹ Ọṣun, ni iku ọkunrin naa fi alafo silẹ fun.
Ọba Agunsoye sọ pe inu oun dun pe oun ṣe imọriri fun OJ nigba to wa laye, gbogbo ilu lo si mi titi lọjọ ti oun fi i joye nitori ọpọlọpọ awọn olorin bii Beautiful Nubia ni wọn waa ṣere lọjọ naa.