Awọn eeyan ilu Lanwa, ni Kwara, pariwo: Ẹ gba wa o, awọn Fulani darandaran ti ya wọlu wa o

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lawọn olugbe ilu Lanwa, nijọba ipinlẹ Moro, nipinlẹ Kwara, figbe ta, wọn ni ominu n kọ awọn pẹlu bawọn Fulani ṣe n rọ kẹti kẹti wọ ilu awọn.

Awọn olugbe ilu Lanwa to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ibẹru-bojo niluu Lanwa ati gbogbo agbegbe rẹ wa bayii, pẹlu bi awọn ajoji Fulani ṣe n ya wọ ilu naa lai mọ ibi ti wọn ti wa. Iya ẹni aadọta ọdun kan to ni ki a ma darukọ oun sọ pe awọn o le sun kawọn di oju mejeeji mọ bayii latari awọn Fulani ti wọn ya wọlu. O tẹsiwaju pe tọkunrin-tobinrin wọn lo n ya wọlu, sugbọn agbara awọn ilu ko ka wọn lati le wọn kuro niluu Lanwa.

Okunrin miiran ti a fọrọ wa lẹnu wo sọ pe awọn to jẹ baalẹ ilu lo gbabọde fun araalu tori pe oun lo gba wọn si ilu, eyi to si buru ju ni pe ile ti awọn Yoruba kan n gbe tẹlẹ, sugbọn ti wọn ti ko kuro ni awọn Fulani naa lọọ de si, ti awọn miiran si ti n kọle ninu wọn si ilu Lanwa. Bakan naa lo ni ọpọ awọn ọmọ ilu Lanwa ni wọn ti n sa kuro niluu bayii.

 

Awọn araalu ti waa rọ ijọba Kwara lati ba wọn le awọn Fulani naa danu tori pe ẹmi ati dukia awọn ti wa ninu ewu bayii.

Leave a Reply