Awọn eeyan ko ri BRT wọ mọ l’Ekoo, owo buruku lawon onidanfo n gba lọwọ wọn

Aderohunmu Kazeem

Ninu idaamu lawọn ara Eko wa bayii, pẹlu bo ṣe ṣoro fun wọn lati ri mọto wọ lọ sibi iṣẹ wọn.

Ogunlọgọ ero lo to sori ila lowurọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni bọsitọọbu mọto BRT, ṣugbọn ti wọn ko ri mọto ijọba kankan ti yoo gbe wọn lọ sibi ti kaluku wọn n lọ.

ALAROYE gbọ pe niṣe lawọn onimọto danfo n lo anfaani bi ko ṣe si mọto BRT loju popo yii lati sọ owo ti wọn n gbe ero dọwọn.

Pupọ ninu awọn araalu ni wọn n kerora bayii, ti wọn si n ṣepe le awọn to fibinu sọ ina si ọpọlọpọ mọto BRT ninu ọgba ti wọn ko wọn si ni Oyingbo ati Berger, nigba ti wahala buruku bẹ silẹ lọsẹ to kọja.

Ni bayii, o jọ pe araalu gan-an lo n jẹrora iwa basejẹ tawọn eeyan kan hu yii, bẹẹ lawọn onidanfo n lo anfaani ọhun lati sọ iye ti wọn n gbe ero di owo gọbọi.

Leave a Reply