Awọn eeyan ma daju o! Wọn si ge ọwọ onibaara lọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ko si bi eeyan yoo ṣe ri ọkunrin onibaara kan nibi to ti n jẹrora nilẹẹlẹ ti aanu ẹ ko ni i ṣe oluwarẹ pẹlu bi awọn ọdaju ẹda kan ṣe ge e lapa mejeeji, ti awọn ageku apa naa si n ṣẹjẹ wọruwọru bíi igba ti wọn ṣẹṣẹ fọbẹ du maaluu lọrun.

Ọkunrin arọ ti ọpọ eeyan mọ bii ẹni mowo lagbegbe Isalẹ-Ijẹbu, niluu Ibadan, yii ni wọn deede ge ọrun ọwọ ẹ mejeeji lọ laaarọ kutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun 2021 yii.

Ohun to tubọ mu ki aanu ikunlẹ abiamọ ṣe awọn to ri i lojumọmọ ọjọ ọhun ni bo ṣe jẹ pe ọkunrin naa ko ti i ku, to jẹ pe niṣe lo kan n jẹrora loju kan naa nibẹ.

Ṣaaju iṣẹlẹ yii, idi lonibaara yii fi maa n wọ rin, to sì maa n ṣagbe kaakiri agbegbe Isalẹ-Ijẹbu pẹlu iranlowo ọwọ mejeeji, nitori arọ ti ko rẹsẹ fi rin ni.

Iwa ika ti awọn adaniloro eeyan hu si i yii ni ko fi da ni loju pe ọkunrin alagbe naa le ru oro nla to n jẹ latara iṣẹlẹ naa la, nitori ko ṣee ṣe fun un lati kuro loju kan ti wọn ti ge e lapa mejeeji lọ naa.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ eeyan to huwa odoro ọhun, awọn to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii gba pe oogun ni wọn fi ọrun ọwọ arọ naa mejeeji ṣe.

Gẹgẹ bi olugbe agbegbe ọhun kan, Jide Ọlaoye, ṣe sọ fakọroyin wa, “Iṣẹ ọwọ awọn to maa n fi ẹya ara eeyan ṣoogun owo lẹ ri yẹn. Iru iṣẹlẹ yẹn pọ lagbegbe yii. Ṣe ẹ mọ pe laipẹ yii ni wọn ba awọn ẹya eeyan kaakiri oju titi Isalẹ-Ijẹbu nibi lọ sọna Ọja’ba.”

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: