Awọn eeyan Oriade ni ọlọpaa ko gbọdọ fi Jombo to n lẹdi apo pọ pẹlu awọn ajinigbe silẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn eeyan ilu Ẹrin Ijeṣa, Ẹrin Oke, Ẹrinmọ Ijeṣa, Ọmọ Ijeṣa ati Iwaraja, nijọba ibilẹ Oriade, nipinlẹ Ọṣun, ti kegbajare si awọn ọlọpaa lati ma ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn afurasi ti wọn mu lori ijinigbe ati idigunjale to n fojoojumọ waye loju-ọna Ileṣa si Akurẹ.

Ninu atẹjade kan ti agbarijọ awọn ọdọ lagbegbe naa, nipaṣẹ aṣoju wọn, Ọgbẹni Alani Ogundipẹ, fi ṣọwọ si ALAROYE, ni wọn ti sọ pe ipe yii di dandan latari bi ọwọ ṣe tẹ ogbologboo afurasi ọdaran kan, Oluwọle Oguntomilọla, ti inagijẹ rẹ n jẹ Jombo, ẹni ti wọn lo ti n daamu alaafia awọn eeyan naa latọjọ to ti pẹ.

Wọn ni aimọye igba lawọn ọlọpaa ti fi panpẹ ofin gbe Jombo, ṣugbọn to jẹ pe ipadabọ rẹ, bii ti Abija ni. Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ko si iṣẹ ibi ti ko pe si ọwọ Jombo, bẹẹ lo ni oniruuru awọn nnkan ija oloro lọwọ.

Wọn ni Oloogbe Ọlapade Agoro lo sọ Jombo di oloye lori ilu ti ko si, to si n lo oye arumọjẹ naa lati maa ta ilẹ onilẹ lai gba aṣẹ, o si tun wa ninu akọsilẹ pe adajọ kootu kan ti ti ọkunrin naa mọle lọdun 2014, ṣugbọn ti wọn tun deede ri i laaarin ilu.

Bẹ o ba gbagbe, laarin oṣẹ to kọja yii ni ọwọ tẹ awọn afurasi meje lẹyin ti awọn ajinigbe tu awọn arinrin-ajo meji ti wọn ji gbe lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, to kọja silẹ. Lara awọn afurasi ti ọwọ awọn ẹṣọ OPC, ọdẹ, Sifu difẹnsi atawọn JTF ba ni Jombo wa.

Wọn fẹsun kan Jombo pe o lẹdi apo pọ mọ awọn Fulani darandaran ti wọn n ṣiṣẹ ibi lagbegbe naa nipa fifi apade ati alude inu igbo naa han wọn, bẹẹ lo si tun maa n gbe ounjẹ fun wọn nitori inu ilu Imọ Ijeṣa lo n gbe.

Gbogbo awọn afurasi naa ni wọn wa lakolo ọlọpaa bayii, ṣugbọn firin-firin ti awọn eeyan agbegbe naa n gbọ pe awọn alagbara kan ti n lọ sagọọ ọlọpaa lati gba beeli Jombo, lo fa a ti wọn fi kegbajare pe ki wọn ma ṣe tu u silẹ fun aabo ẹmi ati dukia awọn araalu.

 

Leave a Reply