Awọn eeyan Oro, ni Kwara, ti sọrọ soke: Yoruba pọnbele ni wa, ‘Orileede Oodua’ la fara mọ o

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

 Awọn eniyan ilu Oro, nipinlẹ Kwara, ṣe iwọde alaafia lati fi beere fun ominira Yoruba ni Ọjọruu, Wesidee, ọsẹ yii, ti wọn si n lọgun pe awọn ki i ṣe Fulani, Oodua tọkan tọkan lawọn.

Iwọde ọhun bẹrẹ ni nnkan bii aago mọkanla ku fẹẹrẹfẹ, ti wọn si ṣe e titi di asaalẹ.

ALAROYE gbọ pe awọn ọmọlẹyin ajafẹtọọ ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ni wọn ṣe agbatẹru iwọde naa niluu Ibadan, ti awọn eeyan Oro ati agbegbe rẹ si tu jade lati fi ero ọkan wọn han lori gbigba ominira ẹya Yoruba kuro lọwọ awọn ijọba arẹnita.

Lara awọn to sọrọ nibi iwọde ọhun ni Ọgbẹni Idris Ọlayinka, ọmọ ilu Ira. O ni gbogbo ibi ti awọn ba de lawọn eeyan maa n sọ fawọn pe ẹru Fulani lawọn ọmọ ipinlẹ Kwara, ṣugbọn ọrọ ko ri bi wọn ṣe ro o, awọn ki i ṣe ẹru Fulani, Yoruba ni awọn. O tẹsiwaju pe awọn ori-ade to wa nipinlẹ Kwara ki i ṣe kekere, Ọlọfa ti ilu Ọfa wa nibẹ, Ẹlẹrin ti Ẹrinle, Onipako ti ilu Saarẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, fun idi eleyii, ọmọ Yoruba ni awọn, tawọn naa si n beere fun ominira Yoruba.

Baalẹ iyana Saarẹ ati gbogbo agbegbe rẹ naa sọrọ, to si ki awọn ọdọ laya pe ki wọn maa tẹsiwaju lati jaja ominira, o ni gbọn-in gbọn-in lawọn alalẹ wa lẹyin wọn, pe ko sewu fun wọn.

Leave a Reply

%d bloggers like this: