Awọn eeyan ya bo ibi tijọba apapọ ko ounjẹ pamọ si ni Irọjo, n’Ileṣa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gbogbo ounjẹ gbigbẹ tijọba apapọ ko pamọ si agbegbe Ọṣun Ankara, ni Irojo, niluu Ileṣa, lawọn araalu tinu n bi ti ko tan bayii.

Silo yii ni wọn kọ lasiko iṣejọba Aarẹ Goodluck Jonathan. O wa kaakiri orileede yii. Ṣe nijọba apapọ maa n ko ounjẹ  sibẹ lasiko ojo, to ba ti di asiko ẹẹrun ni wọn maa n ta a.

Nigba to di pe awọn eeyan agbegbe Ẹdẹ ri ounjẹ Corvid 19 tijọba ko pamọ siluu wọn lonikaluku naa bẹrẹ si i wa gbogbo ibi ti ounjẹ ijọba le wa niluu tiwọn naa.

Abẹnugan ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Honarebu Timothy Owoẹyẹ, to wa lati agbegbe naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

Leave a Reply