Awọn eeyan ya bo ibudo tijọba ko ounjẹ iranwọ korona si ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Bi ki i ba ṣe tawọn agbofinro ti wọn tete da awọn eeyan to n gbiyanju lati wọ ibudo tijọba ipinlẹ Kwara ko awọn ohun iranwọ si lọjọ Ẹti, Furaidee, niṣe ni  wọn iba palẹ gbogbo ẹ mọ.

Ọpọlọpọ araalu ni wọn ya bo ibudo naa to wa ni Ilorin Cargo Terminal, lati le ri ounjẹ atawọn nnkan mi-in gbe, lẹyin ti wọn gbọ pe awọn janduku kan ti bo ibi tijọba ko awọn kinni ọhun si.

Ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nijọba ti figbe ta pe awọn janduku kan tawọn oloṣelu n ṣe onigbọwọ fun, gbero lati fọ ibudo naa, ati lati ba awọn dukia ijọba jẹ.

Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nijọba ti bẹrẹ pinpin awọn ohun iranwọ naa fun awọn to fara gba ọsẹ ti atẹgun ojo ati iṣẹlẹ omiyale ṣe laipẹ yii nipinlẹ Kwara. Ṣadeede lawọn janduku kan ya bo ibudo naa lasiko tawọn aṣoju ijọba n pin awọn ounjẹ naa lọwọ, ti wọn si gbiyanju lati da gbogbo agbegbe naa ru, ki wọn le ri nnkan ko lọ.

Ọrọ ọhun di ohun tawọn agbofinro atawọn janduku n fa mọ ara wọn lọwọ titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Leave a Reply